Old/New Testament
Ọ̀rẹ́
6 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
Ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí a lè bá ọ wá a?
Olólùfẹ́
2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,
sí ibi ibùsùn tùràrí,
láti máa jẹ nínú ọgbà
láti kó ìtànná lílì jọ.
3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,
Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.
Olùfẹ́
4 Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,
ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,
ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5 Yí ojú rẹ kúrò lára mi;
nítorí ojú rẹ borí mi.
Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́
tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.
6 Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,
Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,
gbogbo wọn bí ìbejì,
kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,
rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.
8 Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,
àti ọgọ́rin àlè,
àti àwọn wúńdíá láìníye.
9 Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,
ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,
ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.
Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún
àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.
Ọ̀rẹ́
10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,
tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,
tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
Olùfẹ́
11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi
láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,
láti rí i bí àjàrà rúwé,
tàbí bí pomegiranate ti rudi.
12 Kí èmi tó mọ̀,
àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.
Ọ̀rẹ́
13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulami
padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.
Olùfẹ́
Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,
bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?
7 Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà,
Ìwọ ọmọbìnrin ọba!
Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́
iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2 Ìdodo rẹ rí bí àwo
tí kì í ṣe aláìní ọtí,
ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama
tí a fi lílì yíká.
3 Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì
tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4 Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.
Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni
ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.
Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni
tí ó kọ ojú sí Damasku.
5 Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká
Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká
a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6 Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó
báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
7 Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,
àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
8 Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ;
Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú”
Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,
àti èémí imú rẹ bí i ápù.
9 Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.
Tí ó kúnná tí ó sì dùn,
tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
10 Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,
èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
11 Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,
jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò
12 Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù
láti wo bí àjàrà rúwé
bí ìtànná àjàrà bá là.
Àti bí pomegiranate bá ti rudi,
níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13 Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde
ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,
èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́
tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
8 Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi,
èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!
Èmi ìbá rí ọ ní òde,
èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,
wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
2 Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́
èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá
mi, ìwọ ìbá kọ́ mi
èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu
àti oje èso pomegiranate mi.
3 Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
4 Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà,
Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè,
Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.
Ọ̀rẹ́
5 Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù,
tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀.
Olólùfẹ́
Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ
níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
6 Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì
bí èdìdì lé apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,
ìjowú sì le bí isà òkú
jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
7 Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
Ọ̀rẹ́
8 Àwa ní arábìnrin kékeré kan,
òun kò sì ní ọmú,
kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,
ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
9 Bí òun bá jẹ́ ògiri,
àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.
Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn,
Àwa yóò fi pákó kedari dí i.
Olólùfẹ́
10 Èmi jẹ́ ògiri,
ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́
bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀
bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.
11 Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni
ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú
olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá
ẹgbẹ̀rún fàdákà.
12 Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;
ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni,
igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.
Olólùfẹ́
13 Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,
jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!
Olólùfẹ́
14 Yára wá, Olùfẹ́ mi,
kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,
tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,
lórí òkè òórùn dídùn.
4 Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo. 2 Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀. 3 (A)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 4 Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. 5 Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, 6 (B)Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” 7 Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.
Ìtara Paulu fún àwọn ará Galatia
8 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. 9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? 10 Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. 11 Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.
12 Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dàbí èmi: nítorí èmi dàbí ẹ̀yin: ẹ̀yin kò ṣe mí ní ibi kan. 13 (C)Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. 14 Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu. 15 Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà ha dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, bi o bá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi. 16 Ǹjẹ́ mo ha di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?
17 Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn. 18 Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wá ni fún ohun rere nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan. 19 (D)Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèkéé, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kristi nínú yín. 20 Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsin yìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín.
Hagari àti Sara
21 Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin ohun ti òfin sọ. 22 (E)Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin. 23 (F)Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí.
24 Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari. 25 Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27 (G)Nítorí a ti kọ ọ́ pé,
“Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn
tí kò bímọ,
bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,
ìwọ tí kò rọbí rí;
nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀
yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”
28 Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. 29 (H)Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí. 30 (I)Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.” 31 Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.