Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Òwe 25-26

Àwọn òwe mìíràn ti Solomoni

25 Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,

    tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.

Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;
    láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà
    ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà
Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba
    a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,
    má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì
Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn-ín”
    ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí
    má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn
    bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,
    má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́
    orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ
    ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára
    ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè
    ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an
    ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò
    ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà
    ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba
    bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo
    tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú
    ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ
    ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,
    tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,
    ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.

21 (A)Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;
    bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí
    Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

23 Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá,
    bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé
    ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

25 Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀
    ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́
    ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.

27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,
    bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

28 Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀
    ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.
26 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè
    ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà
    èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè
    èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
    àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
    àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
    àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá
    ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro
    ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa
    ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí
    ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
    ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
11 (B)Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?
    Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

13 Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà
    kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
14 Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,
    ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,
    ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.

17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú
    ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.

18 Bí i asínwín ti ń ju
    ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ
    tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”

20 Láìsí igi, iná yóò kú
    láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,
    bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè
    wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú,
    dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀
    ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́
    nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn
    ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.
    Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,
    ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.

2 Kọrinti 9

(A)Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. (B)Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. (C)Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.

Ìfúnrúgbìn tọkàntọkàn

Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. (D)Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. (E)Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. (F)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:

“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà;
    Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”

10 (G)Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.

12 Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13 (H)Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14 Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15 (I)Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.