Old/New Testament
Àwọn àǹfààní ọgbọ́n mìíràn
3 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,
kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
4 (A)Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
7 (B)Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
àti okun fún àwọn egungun rẹ.
9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,
pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ
10 Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11 (C)Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”
nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
34 (D)Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,
ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
Ọgbọ́n ni o ga jùlọ
4 Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i
2 Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro
Nítorí náà má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀
3 Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,
mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi
4 Ó kọ́ mi ó sì wí pé
“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,
pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5 Gba ọgbọ́n, gba òye,
Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀
6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,
fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.
Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye
8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga
dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ
yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
10 Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,
Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11 Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n
mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12 Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
13 Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
14 Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15 Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ
16 Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú
17 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú
wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
18 Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn
tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19 ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;
wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;
fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi
21 Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú
pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;
22 Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn
àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn
23 Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́
Nítorí òun ni orísun ìyè,
24 Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
26 (E)Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan
27 Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;
pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.
Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè
5 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
2 Kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
ó mú bí idà olójú méjì.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
9 Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ
Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà
àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,
má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà.
20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
21 Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa
Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò
22 Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
23 Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́
ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.
1 (A)Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:
2 (B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.
Ọlọ́run gbogbo ìtùnú
3 (C)Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; 4 (D)Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 5 Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. 7 Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
8 Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. 9 Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: 10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, 11 bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
Paulu yí ìpinnu rẹ̀ padà
12 Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí eyín kò lè kà àti ni mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé. 14 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa.
15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì. 16 (E)Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea. 17 Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?
18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́. 19 (F)Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní. 20 (G)Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi ààmì òróró yàn wá, 22 ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.
23 Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti. 24 Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.