Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Oniwaasu 7-9

Ọgbọ́n

Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ
    ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ
Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀
    ju ibi àsè
nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn
    kí alààyè ní èyí ní ọkàn.
Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,
    ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,
    ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,
    ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,
    ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò
    ni ẹ̀rín òmùgọ̀,
    Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,
    àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,
    sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ
    nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”
    Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára
    ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
    gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
    pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.

13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

“Ta ni ó le è to
    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
    náà ni ó dá èkejì
nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:

Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
    ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
    tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
    kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè
    Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kan
    kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀
    Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára
    ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.

20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé
    tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21 Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ
    bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ
    pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.

23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,

“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”
    ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,
    ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀
    ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25 Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,
    láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n
àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́
    búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ
    obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,
tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté
    tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,
ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27 Oniwaasu wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:

“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
28     Nígbà tí mo sì ń wá a kiri
ṣùgbọ́n tí n kò rí i
    mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún
ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,
    kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.
29 Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:
    Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,
    ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”

Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?
    Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?
Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán
    ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

Pa òfin ọba mọ́

Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,
    àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.
Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,
    ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,
    ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀?
Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró
    nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.
Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,
    bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;
bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,
    bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. 10 Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

11 Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12 Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.

14 Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15 Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.

16 Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17 Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

Àyànmọ́ kan náà fún gbogbo wọn

Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.

Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere
    bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀
bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra
    bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.

Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!

Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú
    ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan
wọn kò ní èrè kankan mọ́,
    àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn
    àti ìlara wọn ti parẹ́:
láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín
    nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe. Máa wọ aṣọ funfun nígbàkúgbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

11 Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn

Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára
    tàbí ogun fún alágbára
bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n
    tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye
    tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;
ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.

12 Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:

Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú
    tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi
    tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

Ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ lọ

13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn: 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ
    ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,
    ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.

2 Kọrinti 13

Àwọn ìkìlọ̀ ìkẹyìn

13 (A)Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀. Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí. Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá ààmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. (B)Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.

Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnrayín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10 Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.

Ìkíni ìkẹyìn

11 Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

12 (C)Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

13 (D)Gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi kí i yín.

14 (E)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.