Old/New Testament
Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́
4 Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,
mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò
sì ní olùtùnú kankan,
agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú
tí wọ́n sì ti lọ,
ó sàn fún wọn ju àwọn
tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju
àwọn méjèèjì lọ:
ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú
tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.
4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò
ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,
àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:
8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;
kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí
kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,
síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,
àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”
Eléyìí náà asán ni
iṣẹ́ òsì!
9 Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,
nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn:
10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,
ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,
ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú
tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!
11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.
Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,
àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,
ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.
Asán ni ipò gíga
13 Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn, 14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. 15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. 16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
Dídúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run
5 Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.
2 Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ,
má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run
Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run
ìwọ sì wà ní ayé,
nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
3 Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.
4 Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. 5 Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. 6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? 7 Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Asán ni ọrọ̀ jẹ́
8 Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. 9 Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.
10 Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,
ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn
pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.
11 Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i
náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i
Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,
kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?
12 Oorun alágbàṣe a máa dùn,
yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.
13 Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.
14 Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.
15 Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.
16 Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá:
Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
kí wá ni èrè tí ó jẹ
nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
17 Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,
pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.
18 Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. 19 Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí. 20 Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.
6 Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. 2 Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.
3 Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́ọ̀rún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. 4 Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. 5 Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. 6 Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?
7 Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni
síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí
8 Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní
lórí aṣiwèrè?
Kí ni èrè tálákà ènìyàn
nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?
9 Ohun tí ojú rí sàn
ju ìfẹnuwákiri lọ
Asán ni eléyìí pẹ̀lú
ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
10 Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,
ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;
kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì
pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ
11 Ọ̀rọ̀ púpọ̀,
kì í ní ìtumọ̀
èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?
12 Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!
Ìṣípayá Paulu àti ẹ̀gún tí n bẹ lára rẹ̀
12 Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. 2 Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. 3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. 4 (A)Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. 5 Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. 6 Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi, 7 (B)àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. 8 Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. 9 Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. 10 (C)Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.
Àníyàn Paulu nípa àwọn ará Kọrinti
11 (D)Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fi ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà aposteli bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan. 12 Ohun kan tí ó ṣe ààmì aposteli, iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ agbára ni wọ́n ṣe ní àárín yín pẹ̀lú sùúrù tó ga. 13 Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.
14 Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. 15 Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 16 (E)Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17 Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? 18 (F)Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí?
19 Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni. 20 (G)Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà. 21 Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má ba à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbèrè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.