Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Òwe 13-15

13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere
    ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.

Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,
    ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́
    Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,
    ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan
    ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀
    ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,
    ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni
    ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀
    ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

15 Òye pípé ń mú ni rí ojúrere
    Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16 Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀
    Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17 Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú
    ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.

18 Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19 Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn
    ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n
    ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22 Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
    ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23 Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá
    ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24 Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

25 Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn
    ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,
    ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.

Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní
    ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
    ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
    nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
    ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.

Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
    ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀
    kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run
    Ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.

12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.

13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;
    ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.

14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
    ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́
    ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.

17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,
    a sì kórìíra eléte ènìyàn.

18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀
    ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.

19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere
    àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.

20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀
    ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.

21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀
    ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.

22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?
    Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.

23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,
    ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.

24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn
    ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.

25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.

26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
    ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.

29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
    ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.

30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
    ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.

31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.

32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,
    kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.

33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye
    kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.

34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,
    ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.

35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n
    ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.

15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde
    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,
    Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè
    ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,
    ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;
    ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú
    ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,
    ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

11 Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa,
    mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.

12 Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí:
    kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká
    ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.

14 Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀
    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.

15 Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,
    ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.

16 Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà
    ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

17 Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà
    sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.

18 Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀
    ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

19 Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà olódodo já geerege ni.

20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,
    ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21 Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;
    ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

22 Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;
    ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà.

23 Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ
    ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

24 Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n
    láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.

25 Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀,
    ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.

26 Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.

27 Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.

28 Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò
    ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

29 Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú
    ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

30 Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,
    ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.

31 Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,
    yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

32 Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,
    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.

33 Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,
    Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

2 Kọrinti 5

Ibùgbé wa ọrun

Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 (B)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (C)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 (D)Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 (E)Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 21 (F)Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.