Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Òwe 30-31

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

30 Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.

Sí Itieli àti sí Ukali.

“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;
    N kò ní òye ènìyàn.
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n
    tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì
Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?
    Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?
Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?
    Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?
Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?
    Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;
    òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn
Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,
    àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;
    má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:
Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;
    má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,
    ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,
Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ
    kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’
Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè
    kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,
    kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.

11 “Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn
    tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn:
12 Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn
    síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
13 Àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,
    tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
14 Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà
    àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ
láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé
    àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.

15 “Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì.
    ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké.

“Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,

mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:

16 Ibojì, inú tí ó yàgàn,

ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,

àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’

17 “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,
    tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá,
ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,
    igún yóò mú un jẹ.

18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,

mẹ́rin tí kò yé mi:

19 Ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú

ipa ejò lórí àpáta

ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun

àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

20 “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin
    ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀
    ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.

21 “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì

lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

22 Ìránṣẹ́ tí ó di ọba

aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ

23 Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ

ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24 “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé

síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;

25 Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,

síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò

26 Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá;

síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;

27 àwọn eṣú kò ní ọba,

síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28 Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú,

síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

29 “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere,

ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:

30 Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun

31 Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́;

àti òbúkọ,

àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

32 “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,
    tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,
    da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33 Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá,
    tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,
    bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”

31 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba,

    ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ.
“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
    Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
    okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli
    kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì
    kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle
Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí
    kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n
Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
    wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;
Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
    kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnrawọn
    fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun
Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
    jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
    Ó níye lórí ju iyùn lọ
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
    kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
    Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
    ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
    ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
    àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
    nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
    apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́
18 Ó rí i pé òwò òun pé
    fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
    nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
    ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
    níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
    ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
    ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
    ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
    kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
    ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
    ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
    kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.

2 Kọrinti 11:1-15

Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké

11 (A)Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. (B)Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. (D)Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.

(E)Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. (F)Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo. (G)Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. (H)Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10 (I)Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 (J)Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.

12 (K)Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13 Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14 Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15 Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.