Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Òwe 1-2

Èròǹgbà àti kókó-ọ̀rọ̀

Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.

Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,
    Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,
    àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,
    ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,
    sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,
    àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.

Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ṣàfẹ́rí ọgbọ́n

Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,
    má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ
    àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.

10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,
    má ṣe gbà fún wọn.
11 Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;
    jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,
    jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
12 Jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,
    àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13 A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí
    a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa;
14 Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,
    a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà”
15 Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,
    má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;
16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,
    wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
17 Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀,
    ní ojú ẹyẹ!
18 Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.
    Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà
19 Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;
    yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.

Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀

20 (A)Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó
    ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;
21 Láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde
    Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?
    Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?
    Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,
    Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín
    kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.
24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè
    kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,
25 Níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,
    tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,
26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;
    èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.
27 Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,
    Nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,
    nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

28 “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;
    wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
29 Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀
    tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.
30 Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi
    tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
31 Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn
    wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún
32 Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n
    ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
33 Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu
    yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

Èrè ìwà rere tí ọgbọ́n ń mú wá

Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,
    tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n
    tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,
    tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà
    tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,
    ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,
    láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá
Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,
    Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́
    Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,
    àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ
    ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ
11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́
    òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.

12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
    lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin
    láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,
    tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́
    tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.

16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,
    àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀
    tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú
    ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.

20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere
    kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà
    àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà
    a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.

1 Kọrinti 16

Ìkójọpọ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

16 (A)Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. (B)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (C)Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

Ìbéèrè ti ara ẹni

(D)Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia. Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ. (E)Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́ (F)Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti. (G)Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

10 (H)Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. 11 Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

12 (I)Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

13 (J)Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.

15 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́. 16 Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá. 17 Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un. 18 Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

Ìkíni ìkẹyìn

19 (K)Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín.

Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

20 (L)Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín.

Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

21 (M)Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

22 (N)Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

23 (O)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

24 Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.