Old/New Testament
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa”.
54 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:
dá mi láre nípa agbára rẹ.
2 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;
fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3 Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.
Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,
àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
4 Kíyèsi i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi;
Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,
pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
5 Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;
pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,
èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,
nítorí tí ó dára.
7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo
ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.
55 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
2 Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
kí ń sì dúró sí aginjù;
8 Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
èmi ìbá sápamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.
16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.
Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.
56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà
sí mi, wọn ń ni mi lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba
Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
Ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀:
11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run
3 Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? 2 (A)Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.
3 Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? 4 (B)Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”
5 (C)Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn). 6 Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? 7 Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 8 (D)Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.
Kò sí olóòtítọ́ kan
9 (E)Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 10 (F)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan
11 Kò sí ẹni tí òye yé,
kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
12 Gbogbo wọn ni ó ti yapa,
wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;
kò sí ẹni tí ń ṣe rere,
kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
13 (G)“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:
ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”
“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”
14 (H)“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”
15 (I)“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:
16 ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.
17 Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”
18 (J)“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”
19 (K)Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 20 (L)Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.
Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́
21 (M)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; 22 (N)Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 23 (O)Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: 24 (P)Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: 26 (Q)Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.
27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 28 (R)Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 29 (S)Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: 30 (T)Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 31 (U)Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.