Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 34-35

Elihu pe Jobu níjà

34 Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé:

“Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
    kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.
Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,
    bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.
Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa;
    ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.

“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi;
    Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,
    bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi,
    ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’
Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu,
    tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó
    sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,
    tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’

10 “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,
    ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:
Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú,
    àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
11 Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,
    yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.
12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;
    bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
13 Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́,
    tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?
14 Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀
    tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,
    ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.

16 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye,
    gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.
17 Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí?
    Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘ènìyàn búburú ní ìwọ,’
    tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘ìkà ni ẹ̀yin,’
19 Mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé
    tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,
    nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
20 Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,
    àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;
    a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.

21 “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,
    òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
22 Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,
    níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sápamọ́ sí.
23 Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,
    kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
24 Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí,
    a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
25 nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn,
    ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26 Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn
    níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27 nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i,
    wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
28 kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
29 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi?
    Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i?
Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
30     Kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba
    kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.

31 “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé,
    èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?
32 Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi
    bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
33 Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?
    Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́,
ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi.
    Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀;
    Pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!

34 “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi,
    àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
35 ‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀,
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
36 Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin,
    nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú:
37 Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;
    ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa,
    ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

Olóòtítọ́ ni Ọlọ́run

35 Elihu sì wí pe:

“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,
    òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ,
    tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

“Èmi ó dá ọ lóhùn
    àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì
    bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí?
    Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un,
    tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ;
    òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe;
    wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
10 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé,
    ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
11 Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ,
    tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
12 Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn
    nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
13 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán;
    bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
14 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i,
    ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ,
    ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
15 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni,
    òun kò ni ka ìwà búburú si?
16 Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀
    lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”

Ìṣe àwọn Aposteli 15:1-21

Àjọ ìgbìmọ̀ ní Jerusalẹmu

15 (A)Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.” Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin. Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”

Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù? 11 Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”

12 Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà. 13 Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi: 14 Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀. 15 Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

16 (B)“ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,
    èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀:
èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,
    èmi ó sì gbé e ró.
17 Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,
    àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’
ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,
18     ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

19 “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu. 20 Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ́hìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀. 21 Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.