Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 36-37

36 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,
    nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,
    èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké
    nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì
    gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,
    ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,
    ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;
    àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a
    sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
Nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,
    wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.
10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,
    ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,
    wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,
    àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,
    wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,
    wọ́n á sì kú láìní òye.

13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
    wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
    ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
    a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.

16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
    sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
    ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
    ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;
    láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.
19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?
    Tàbí ipa agbára rẹ?
20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké
    àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú;
    Nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;
    ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?
23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,
    tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?
24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,
    ti ènìyàn ni yín nínú orin.
25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;
    ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè,
26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,
    kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,
28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,
    tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.
29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,
    tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká
    ó sì bo ìsàlẹ̀ Òkun mọ́lẹ̀.
31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;
    ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì
    ó sì rán an sí ẹni olódì.
33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;
    ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!

Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí

37 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
    ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
    àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
    Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
    ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
    nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
    ohùn ńláńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
    àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
    ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
    wọn a sì wà ni ipò wọn.
Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
    àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
    ibú omi á sì súnkì.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
    a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
    kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
    tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
    tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;
    dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,
    tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,
    iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,
    nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,
    tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?

19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;
    nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?
    Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí
    oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,
    ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;
    lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;
    nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,
    òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”

Ìṣe àwọn Aposteli 15:22-41

Ìwé tí àwọn àjọ ìgbìmọ̀ kọ sí àwọn onígbàgbọ́ aláìkọlà

22 Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin. 23 Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé:

Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà,

Tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria: àti ní Kilikia.

24 Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà, (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́) ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ: 25 Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa. 26 Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi. 27 Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín. 28 Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù le é yin lórí, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì; 29 í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere.

Àlàáfíà.

30 Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Antioku. Nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ papọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn. 31 Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà. 32 Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le. 33 Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. 34 (Ṣùgbọ́n ó wu Sila láti gbé ibẹ̀.) 35 Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.

Ìjà láàrín Paulu àti Barnaba

36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòókan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.” 37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku. 38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà. 39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi. 40 Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin. 41 Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.