Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 57-59

Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
    títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
    yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
    Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
    mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
    ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
    kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
    a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

(A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
    ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
Jí, ìwọ ọkàn mi!
    Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
    Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.

Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
    òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.

11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
    kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
    ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
    ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
    ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
    lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
Oró wọn dàbí oró ejò,
    wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
    bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
    ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
    nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
    bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
    bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
    nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
    “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
    lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

59 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;
    dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú
    kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!
    Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi
Kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
    Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
Olúwa Ọlọ́run Alágbára,
    Ọlọ́run Israẹli,
dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
    má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.

Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
    wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:
    wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,
    wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín
    Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;
    nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10     Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.
    Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,
    kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.
Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,
    kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,
    ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,
    kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.
Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,
13     Pa wọ́n run nínú ìbínú,
    run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.
Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé
    pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

14 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọn ń gbó bí àwọn ajá
    wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.
15 Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ
    wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,
    n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;
nítorí ìwọ ni ààbò mi,
    ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;
    ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.

Romu 4

Abrahamu gba ìdáláre nípa ìgbàgbọ́

Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. (A)Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. (B)Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

(C)Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. (D)Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo. Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́.

(E)Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn
    ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”

Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 10 Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. 11 (F)Ó sì gbé ààmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12 Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.

13 (G)Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. 14 (H)Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára: 15 (I)Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.

16 Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, 17 (J)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.

18 (K)Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19 (L)Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara: 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run; 21 Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22 (M)Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. 23 (N)Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. 24 Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. 25 (O)Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.