Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107-109

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
    wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
    wọn ó máa gbé
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
    ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
    tí wọn lè máa gbé
Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
    ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
    ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.

10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,
    a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
11 Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀
    Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;
    wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí
    yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
    ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú
    òkùnkùn àti òjìji ikú,
    ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì
    ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.

17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
    wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
    wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú
    ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
    ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
    kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀
    ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
    tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
    tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
    nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
    ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
    ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
    bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
    ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
    Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
    kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye
    kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.

39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,
    ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù
40 Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé
    ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira
    ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran
42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn
    ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
    kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Orin. Saamu ti Dafidi.

108 (A)Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin
    èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin
Jí ohun èlò orin àti haapu
    èmi ó jí ní kùtùkùtù
Èmi ó yìn ọ́, Ọlọ́run, nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn
Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ
    ju àwọn ọ̀run lọ
    àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀
Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,
    àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

(B)Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
    fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
    kí o sì dá mi lóhùn
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé:
    “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
    èmi yóò sì wọn Àfonífojì Sukkoti kúrò.
Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
    Efraimu ni ìbòrí mi,
    Juda ni olófin mi,
Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
    lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
    Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.
    Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,
    nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin
    nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún
    Má ṣe dákẹ́
Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
    ti ya ẹnu wọn sí mi
    wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
    wọ́n bá mi jà láìnídìí
Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
    ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
    àti ìríra fún ìfẹ́ mi.

Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
    jẹ́ kí àwọn olùfisùn
    dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
    kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
(C)Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú
    kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀
Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
    kí aya rẹ̀ sì di opó
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
    kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
    jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
    tàbí kí wọn káàánú lórí
    àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
    kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
    ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa
    Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
    kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
    ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
    kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
    bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní
    ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
    àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
    ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ
    Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
    àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
    mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
    ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 (D)Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
    nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
    wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre;
    Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
    kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.

30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
    ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín
31 Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní
    láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.

1 Kọrinti 4

Àwọn aposteli Kristi

(A)Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́. Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. (B)Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi. (C)Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

(D)Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! (E)Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10 (F)Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11 (G)Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12 (H)Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15 (I)Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. 17 (J)Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.

18 Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín. 19 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní. 20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára. 21 (K)Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàṣán, tàbí ni ìfẹ́, àti ẹ̀mí tútù?

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.