Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 70-71

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
    àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
    lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
    nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
    wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
    bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
    Olúwa Olódùmarè;
    èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
    títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
    àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
    ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
    Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
    ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
    láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
    ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
    nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
    èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Romu 8:22-39

22 (A)Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23 (B)Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. 24 (C)Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27 (D)Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29 (E)Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀ 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

Jíju aṣẹ́gun lọ

31 (F)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (G)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (H)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (I)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (J)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
    À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

37 (K)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.