Old/New Testament
119 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,
2 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
3 Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
4 Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
5 Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
6 Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
7 Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
8 Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀:
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
9 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12 Ìyìn ni fún Olúwa;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
Ohun ìyanu tí o wà nínú òfin rẹ̀
17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
Òfin Ọlọ́run ní ìrètí
49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
Ọlọ́run ni ìpín wa
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
Kọ́ mi ní òfin rẹ.
Ìpọ́njú mu ni mọ òfin Ọlọ́run
65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
Wíwá àlàáfíà
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
20 Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.
21 Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. 22 (A)Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. 23 (B)A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. 24 Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ nípa àwọn àpọ́n
25 Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá: èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo. 26 Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà. 27 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí. 28 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí.
29 (C)Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; 30 àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, 31 àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ.
32 (D)Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35 Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.
36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. 38 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ.
39 (E)A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. 40 (F)Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.