Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 89-90

Maskili ti Etani ará Esra.

89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
    pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
    pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
(A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
    mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
    èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
    òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
    Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
    ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
    ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
    nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
    tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
    ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
    Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
    agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
    Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
    wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
    nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
    ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
    “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
    èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (B)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
    pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
    apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
    àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
    èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
    àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
    àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (C)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
    Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
    àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
    àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
    tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
    tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
    àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán:
33 Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
    àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37 (D)A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
    àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela.

38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;
    ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni ààmì òróró rẹ.
39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;
    ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku
40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀
    ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;
    ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;
    ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,
    ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,
    ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
    ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.

46 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?
    Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?
    Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
    nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
    Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
49 Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
    tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
50 Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
    bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
51 Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa,
    tí wọn gan ipasẹ̀ Ẹni ààmì òróró rẹ.

52 Olùbùkún ní Olúwa títí láé.
Àmín àti Àmín.

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run

90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
    àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
    wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
(E)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
    bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
    wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
    ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

A pa wá run nípa ìbínú rẹ
    nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
    àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
    àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
    bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
    agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
    àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Romu 14

Aláìlera àti alágbára

14 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀. Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. (A)Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á. Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.

(B)Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. (C)Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. (D)Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.

10 (E)Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 11 (F)A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

“ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí,
‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;
    gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”

12 Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

13 (G)Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín. 14 Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. 15 (H)Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. 16 (I)Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. 17 Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, 18 nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.

19 (J)Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró. 20 (K)Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀. 21 (L)Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú.

22 (M)Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.