Add parallel Print Page Options

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run

90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
    àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
    wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
(A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
    bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
    wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
    ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

A pa wá run nípa ìbínú rẹ
    nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
    àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
    àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
    bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
    agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
    àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
    “Òun ni ààbò àti odi mi,
    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
    ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (B)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (C)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
    Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
    aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
    bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
    búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
    nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
    ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
    òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
    ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
    tí ó dìde sí mi.

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”
93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
    ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
    àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
    kò sì le è yí.
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
    ìwọ wà títí ayérayé.

A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
    Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
    Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
    ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
    Olúwa ga ní ògo.

Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
    ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
    fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
94 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
    Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
    san ẹ̀san fún agbéraga
    ohun tí ó yẹ wọ́n.
Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
    Olúwa
tí àwọn ẹni búburú
    yóò kọ orin ayọ̀?

Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
    gbogbo àwọn olùṣe búburú
kún fún ìṣògo.
Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:
    wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
    wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,
Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;
    Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn
    ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
    Ẹni tí ó dá ojú?
Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
    Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 (D)Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;
    ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
    ìwọ bá wí, Olúwa,
ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ;
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
    títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀;
Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
    àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
    dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.

16 Ta ni yóò dìde fún mi
    sí àwọn olùṣe búburú?
    Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
    èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́
18 Nígbà tí mo sọ pé “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
    Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
    ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
    ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
    wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,
    àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
    tí mo ti ń gba ààbò.
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
    yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
    Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
    orin àti ìyìn.

Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
    ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
    àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
    Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
(E)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
    àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

    Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
    àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
    tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
    mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
    ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
96 (F)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
    a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
    ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
    jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12     Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13     Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
    àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
97 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
    jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
    òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
    ayé rí i ó sì wárìrì
Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,
    níwájú Olúwa gbogbo ayé.
Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

(G)Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
    àwọn tí ń fi ère gbéraga,
    ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
    inú àwọn ilé Juda sì dùn
    Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa
Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
    ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
    Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
    ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
    àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
    kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
    nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
    o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
    o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
    gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
    iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
    ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
    ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
    ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
    ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
    Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
    àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
99 Olúwa jẹ ọba;
    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
Olúwa tóbi ní Sioni;
    Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
    tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.

Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
    ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
    ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
    ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
    Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
    wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
    wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
    ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
    ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n
Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
    kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
    nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Ti Dafidi. Saamu.

101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
    sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
    ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?

Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
    pẹ̀lú àyà pípé.
Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
    iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.

    Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
    Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
    òun ní èmi yóò gé kúrò
ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
    òun ní èmi kì yóò faradà fún.

Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
    kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
    òun ni yóò máa sìn mí.

Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
    kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
    gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
    kúrò ní ìlú Olúwa.

Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa

102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
    Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
    ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
    nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.

Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
    egungun mi sì jóná bí ààrò
Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
    mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
Nítorí ohùn ìkérora mi,
    egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
    èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
    àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
    èmi sì rọ bí koríko.

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
    ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
    nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
    àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
    wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
    kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
    àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
    láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
    àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
    àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
    ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
    ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
    “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (H)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
    gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
    wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
    ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
    a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”

Ti Dafidi.

103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
    tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
    ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
    kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
    gbogbo àwọn tí a ni lára.

Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
(I)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
    ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
    bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
    bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
    ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
    ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
    kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (J)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
    Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
    àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
    ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
    tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
    ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
    ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
    ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
    Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
    ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
(K)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
    Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
    tí a kò le è mì láéláé.
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
    àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
    nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
    wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
    láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì;
    tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
    àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
    wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
    a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
    àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò
    kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
    òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
    àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,
    kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
    bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
    àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

19 Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò
    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
    nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
    wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
    wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
    tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
    ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
    àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
    wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
    ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
    wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
    ni a dá wọn,
    ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
    kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
    ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
    bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.
105 (L)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
    Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
    sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
    Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
Olúwa àti ipá rẹ̀;
    wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
    ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
    ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
    ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

(M)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
    ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
    ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
    sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
    gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

12 Nígbà tí wọn kéré níye,
    wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
    láti ìjọba kan sí èkejì.
14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
    ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
    ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
    Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
    a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
    títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
    àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
    aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
    ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
    kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Israẹli wá sí Ejibiti;
    Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
    ó sì mú wọn lágbára jù
    àwọn ọ̀tá wọn lọ
25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
    láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀
    àti Aaroni tí ó ti yàn
27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
    ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
    wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
    ó pa ẹja wọn.
30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
    èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
    ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32 Ó sọ òjò di yìnyín,
    àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
    ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
    àti kòkòrò ní àìníye,
35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
    wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
    ààyò gbogbo ipá wọn.
37 Ó mú Israẹli jáde
    ti òun ti fàdákà àti wúrà,
    nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
    nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
    àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
    ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
    gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
    àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
    pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
    wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
    kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
106 (N)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
    Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
    ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
    Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

Rántí mi, Olúwa,
    Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
    wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
    kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
    ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.

Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
    àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
    a sì ti hùwà búburú
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
    iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
    gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa
Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
    láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀
O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ;
    o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù
10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn
    láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n
11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni
    kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
    wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.

13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
    wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
    nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
    ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
    pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
    ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
    iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
    wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
    sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
    ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
    àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
    bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
    tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà
    wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn
    wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
    kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27 Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè
    láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.

28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,
    wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà
29 Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe
    àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,
    àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán
31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti
    fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,
    ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run.
    Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.

34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run
    gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn,
35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn
36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn
    tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ
    àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
    Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn
ọmọbìnrin wọn.
    Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀
39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
    wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
    àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
    wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
    Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
    wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
    nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
    Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
    ó mú wọn rí àánú.

47 (O)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
    kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
    láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!