Old/New Testament
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
6 Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
nítorí ó dára sí mi.
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
14 (A)(B) Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
“Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.
2 Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
3 Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
kò sí ẹnìkan.
4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?
Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
wọn kò sì ké pe Olúwa?
5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.
7 Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
21 Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” 22 Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.
Ìrúkèrúdò ní Efesu
23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. 24 Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; 25 Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. 26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. 27 Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”
28 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!” 29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò. 30 Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un. 31 Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà.
32 Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀. 33 Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn. 34 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!”
35 Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀? 36 Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun. 37 Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa. 38 Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn. 39 Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́. 40 Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.” 41 Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.