Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 49-50

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
    Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
    tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
    èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
    Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
    tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
    padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
    kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
Ní ti kí ó máa wà títí ayé
    láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
    ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
    ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
    gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
    tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
    ikú yóò jẹun lórí wọn;
ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
    jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀;
Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
    isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
    kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
    Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
    ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
    Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
    àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Saamu ti Asafu

50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
    sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
    láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Ọlọ́run ń bọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
    àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
    kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
    àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
    Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
    tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
    àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
    àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
    nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
    mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
    tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
    ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
    ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
    ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
    ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
    ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
    èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
    kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Romu 1

Ọ̀rọ̀ ìkíni Paulu sí àwọn àyànfẹ́

(A)Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìhìnrere Ọlọ́run, ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́. Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara, ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa. (B)Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.

(C)Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.

Ìfojúsọ́nà Paulu láti bẹ Romu wò

(D)Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé. Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìhìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi 10 (E)nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

11 Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, 12 èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. 13 (F)Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.

14 (G)Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìhìnrere Ọlọ́run sí i yín.

16 (H)Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 17 (I)Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé

18 (J)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 (K)Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

21 (L)Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 (M)wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

26 Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. 27 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

28 Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: 29 Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. 30 Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31 aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú: 32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.