Old/New Testament
Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.
7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9 (A)Ọlọ́run Olódodo,
Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (B)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
9 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
7 Olúwa jẹ ọba títí láé;
ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8 (C)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.
Ní Kọrinti
18 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Paulu jáde kúrò ni Ateni lọ sí Kọrinti. 2 Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn. 3 Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn. 4 Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà.
5 Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà. 6 Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”
7 Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́. 8 Krisipu, olórí Sinagọgu, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọrinti, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitiisi wọn.
9 (A)Olúwa sì sọ fún Paulu lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, ṣá máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ̀ mọ́: 10 Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.” 11 Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrín wọn.
12 Nígbà tí Gallioni sì jẹ baálẹ̀ Akaia, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dìde sí Paulu wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”
14 Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù; 15 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrayín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.” 16 Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́. 17 Gbogbo àwọn Giriki sì mú Sostene, olórí Sinagọgu, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gallioni kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.
Priskilla, Akuila àti Apollo
18 Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea: nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́. 19 Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀. 20 Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀. 21 Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì lọ kúrò láti Efesu. 22 Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Kesarea, ó gòkè lọ si Jerusalẹmu láti kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Antioku.
23 Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀, ó n lọ, láti káàkiri ni agbègbè Galatia àti Frigia, o ń mu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.
24 Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀; 25 Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu dáradára; kìkì bamitiisi tí Johanu ní ó mọ̀. 26 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sinagọgu. Nígbà tí Akuila àti Priskilla gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀, wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.
27 Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Akaia, àwọn arákùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀. 28 Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé mímọ́ pé, Jesu ni Kristi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.