Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 22-24

Èsì Elifasi

22 Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

(A)“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?
    Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?
Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?
    Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù
    Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?
Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi,
    àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?
Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí,
    ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.
Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu,
    ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.
Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀,
    ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.
Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo;
    Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.
10 Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri,
    àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,
11 Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran;
    Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12 “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?
    Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!
13 Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?
    Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?
14 Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un,
    tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.
15 Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn
    ènìyàn búburú tí rìn?
16 A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn;
    ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn;
17 Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!
    Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’
18 Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!
    Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!
19 Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,
    àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,
20 ‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,
    iná yóò sì jó oró wọn run.’

21 “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
    nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
22 Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
    kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
23 Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró:
    Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
24 Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀
    lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò,
25 Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
    àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
26 Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
    ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
27 Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
    ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
    ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
29 Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
    nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’
    Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
30 Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,
    a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Èsì Jobu

23 Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé:

“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
    ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
    Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
    ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá
    mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
    Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
    níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,
    òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,
    ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10 Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,
    nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11 Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;
    ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,
    èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.

13 “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
    Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14 Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
    nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16 Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
    Olódùmarè sì ń dààmú mi.
17 Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

Ìbéèrè Jobu

24 “Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?
    Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀,
    wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.
Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba
    lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
    àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́.
Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
    ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,
    wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,
    tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
    wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,
    wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.
10 Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;
    àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,
11 Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
    tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
12 Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
    ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
    síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.

13 “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;
    Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14 Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,
    a sì pa tálákà àti aláìní,
    àti ní òru a di olè.
15 Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;
    ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’
    ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16 Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,
    tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán,
    wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17 Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn;
    nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.

18 “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi;
    ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;
    òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19 Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́,
    bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.
20 Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò
    ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀,
a kì yóò rántí ènìyàn búburú
    mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi;
21 Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí
    kò ṣe rere sí opó.
22 Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára,
    bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
23 Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un,
    àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn,
    ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24 A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ;
    a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn,
    a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.

25 “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké,
    tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”

Ìṣe àwọn Aposteli 11

Peteru ṣàlàyé nípa àwọn ìhùwàsí rẹ̀

11 Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́ wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”

(A)Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, “Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi. Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run. Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’

“Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’

“Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kejì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’ 10 Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.

11 “Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi. 12 Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà: 13 Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru; 14 ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’

15 “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe. 16 (B)Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’ 17 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”

18 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”

Ìjọ ní Antioku

19 (C)Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21 Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.

22 Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23 Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.

25 Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, 26 nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”

27 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá sí Antioku. 28 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.) 29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. 30 Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.