Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 46-48

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
    ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.

Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
    ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
    àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
    ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.

Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
    Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
    Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
    ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!

Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
    Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
    gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
    òun ni ó ga jùlọ.

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

(A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
    ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
    ní ìlú ọba ńlá.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
    ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
    wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
    a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
    ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
    wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
    Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ní ìlú Ọlọ́run wa,
    Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
    àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
    ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
    kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
    nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
    ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
    kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
    Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Ìṣe àwọn Aposteli 28

Erékùṣù ni Mẹlita

28 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọbiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.

Paulu dé sí Romu

11 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí ààmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu. 12 Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sirakusi, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli. 14 A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu. 15 Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le. 16 Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.

Paulu wàásù ní Romu ní abẹ́ ẹ̀ṣọ́

17 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Paulu pe àwọn olórí Júù jọ. Nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti ṣe pé èmi kò ṣe ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, síbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Romu lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerusalẹmu wá. 18 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi. 19 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Kesari, kì í ṣe pe mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi. 20 Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Israẹli ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”

21 Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Judea nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ. 22 Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ẹgbẹ́ ìlànà yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”

23 Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́. 24 Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́. 25 Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé:

26 (A)‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,
“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”
27 Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,
    etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,
    ojú wọn ni wọn sì ti di.
Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
    kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́,
    àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

28 (B)“Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn kèfèrí wọ́n ó sì gbọ́. 29 Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jiyàn púpọ̀.”

30 Paulu sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá. 31 Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu Kristi Olúwa, ẹnìkan kò si dá a lẹ́kun.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.