Old/New Testament
Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ Jobu
30 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,
àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà
baba ẹni tí èmi kẹ́gàn
láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
2 Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,
níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
3 Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn
wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ
ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.
4 Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó;
gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.
5 A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn,
àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6 A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta Àfonífojì,
nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7 Wọ́n ń dún ní àárín igbó
wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
8 Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,
àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;
àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
10 Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,
wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
11 Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;
àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
12 Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;
wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò,
wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
13 Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú;
wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀,
àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
14 Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru;
ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
15 Ẹ̀rù ńlá bà mí;
wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù,
àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
16 “Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;
ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
17 Òru gún mi nínú egungun mi,
èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
18 Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,
ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.
19 Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,
èmi sì dàbí eruku àti eérú.
20 “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;
èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
21 Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́
agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
22 Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
23 Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
24 “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25 Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
26 Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;
nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
27 Ikùn mí n ru kò sì sinmi;
Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
28 Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;
èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
29 Èmi ti di arákùnrin ìkookò,
èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
30 Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;
egungun mi sì jórun fún ooru.
31 Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,
àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.
Àwíjàre Jobu
31 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,
èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?
2 Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?
Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.
3 Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,
àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
4 Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,
òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
5 “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,
tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;
6 (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,
kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
7 Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,
tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,
tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,
8 Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,
àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.
9 “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,
tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10 Kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,
kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11 Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú
àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀
12 Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,
tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
13 “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi
tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,
nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
14 Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?
Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
15 Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?
Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
16 “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,
tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,
17 Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,
tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
18 nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,
èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
19 Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,
tàbí tálákà kan láìní ìbora;
20 Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,
tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
21 Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,
nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22 Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,
kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,
àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
24 “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,
tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’
25 Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,
àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọpọ̀;
26 Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,
tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
27 Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fi
ẹnu mi kò ọwọ́ mi:
28 Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò.
Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
29 “Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi.
Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.
30 Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀
nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.
31 Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé,
ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?
32 (Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí;
èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.)
33 Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá,
ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.
34 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí?
Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù?
Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?
35 (“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí!
Kíyèsi i, ààmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn!
Kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ!
36 Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi,
èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
37 Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un,
bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
38 “Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi
tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
39 Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó
tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
40 kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama,
àti èpò búburú dípò ọkà barle.”
Ọ̀rọ̀ Jobu parí.
26 (A)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (B)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:
“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
lónìí ni mo bí ọ.’
34 (C)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:
“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
35 (D)Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé:
“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. 39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. 40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
41 (E)“ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;
nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín,
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”
42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. 43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.
46 Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47 (F)Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé:
“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,
kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”
48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.
49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. 50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn. 51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu. 52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.