Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 32-33

Ọ̀rọ̀ Elihu

32 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀. Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.

Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé:

“Ọmọdé ni èmi,
    àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
    mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,
    àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
    àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
Ènìyàn ńláńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

10 “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
    èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
11 Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;
    Èmi fetísí àròyé yín,
nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;
12     àní, mo fiyèsí yín tinútinú.
Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;
    tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
13 Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí;
    Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
14 Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.

15 “Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́,
    wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16 Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́;
    wọn kò sì dáhùn mọ́.
17 Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi,
    èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
18 Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,
    ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
19 Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò;
    ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
20 Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,
    èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
21 Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan,
    bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
22 Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀,
    Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

Elihu bá Jobu sọ̀rọ̀

33 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ,
    gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi,
    ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi,
    ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi,
    àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.
Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn,
    tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi;
Kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà;
    láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.
Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ;
    bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.

“Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi,
    èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi;
    bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
10 Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi;
    ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
11 Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà;
    o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’

12 “Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà!
    Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
13 Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé,
    òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
14 Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan,
    àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
15 Nínú àlá, ní ojúran òru,
    nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ,
    ní sísùn lórí ibùsùn,
16 Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn,
    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
17 Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀;
    Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
18 Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú,
    àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.

19 “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀;
    pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
20 bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ,
    ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
21 Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́
    egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
22 Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú,
    ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
23 Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀,
    ẹni tí ń ṣe alágbàwí,
    ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
24 Nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé,
    gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú;
    èmi ti rà á padà.
25 Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré,
    yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
26 Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀,
    o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀,
    òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
27 Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé,
    ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po,
    a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
28 Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò,
    ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’

29 “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run
    máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
30 Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú,
    láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.

31 “Jobu, kíyèsi i gidigidi kí o sì fetí sí mi;
    pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́
32 Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn;
    máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
33 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi;
    pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

Ìṣe àwọn Aposteli 14

Ní Ikoniomu

14 Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere.

Ní Lysra àti Dabe

Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. 10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.

11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” 12 Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. 13 Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.

14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: 15 (A)“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. 17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” 18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.

19 (B)Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú. 20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.

Ìpadàbọ̀ sí Antioku ti Siria

21 Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìhìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku, 22 wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run. 23 Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́. 24 Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí pamfilia. 25 Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia:

26 Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí 27 Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà. 28 Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.