Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 14-16

Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀

14 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
    ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
    ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni?
    Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
    Kò sí ẹnìkan!
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
    iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè
    sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
    ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
    àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
    tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
    yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;
    Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.

Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn

11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
    àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
    títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
    wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
    kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
    ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
    Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
    fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
    ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
    ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
    ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.

18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
    a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
    mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
    ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
    Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
    wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí
    ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

Elifasi tako ọrọ̀ Jobu

15 Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí
    ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?
Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní
    èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,
    ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀
    rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
    àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.

“Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?
    Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí, tàbí
    ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?
    Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
10 Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,
    tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
11 Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?
    Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
12 Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,
    kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.
13 Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,
    tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

14 “Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,
    àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
15 Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,
    àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,
16 mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,
    tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.

17 “Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;
    Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18 ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti
    ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,
19 Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,
    ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20 Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,
    pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,
    àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21 Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;
    nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22 Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;
    a sì ṣà á sápá kan fún idà.
23 Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?
    Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24 Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un
    bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.
25 Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì
    sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,
26 Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,
    àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.

27 “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀
    lójú, o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28 Òun sì gbé inú ahoro ìlú,
    àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé
    mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.
29 Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò
    lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30 Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;
    ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,
    àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.
    Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32 A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,
    ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33 Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,
    yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
34 Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè
    yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35 Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,
    ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”

Ìdáhùn Jobu fún Elifasi

16 Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé:

“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
    ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
    Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
    bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,
èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,
    èmi a sì mi orí mi sí i yín.
Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni
    ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.

“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
    bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
    Ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
    àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
    ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
    ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
    Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
    Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni
    búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
    ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe ààmì ìtafàsí rẹ̀;
13     àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
    ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
    ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
    mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
    òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
17 Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́
    mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.

18 “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
    kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
19 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
    ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
    ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
21 Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
    bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.

22 “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,
    nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.

Ìṣe àwọn Aposteli 9:22-43

22 Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.

23 Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á 24 (A)Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

26 Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. 27 Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. 28 Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. 30 Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu.

31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.

Aenea àti Dọkasi

32 Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33 Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34 Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35 Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.

36 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe. 37 Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè. 38 Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”

39 Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.

40 Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41 Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42 Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́. 43 Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.