Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kronika 21-22

Jehoramu ọba Juda

21 (A)Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.

Jehoramu Ọba Juda

Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli. (B)Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu. Ó ṣe búburú lójú Olúwa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí Olúwa ti dá fún Dafidi kì í ṣe ìfẹ́ Olúwa láti pa ìdílé Dafidi run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.

Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. 10 Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda.

Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. 11 Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.

12 Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé:

“Èyí ní ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. 13 Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ. 14 Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí, Ọlọ́run ti fẹ́rẹ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn ńlá. 15 Ìwọ tìkára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ”

16 Olúwa ru ìbínú àwọn ará Filistini àti àwọn Arabia tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá àwọn ará Kuṣi sí Jehoramu. 17 Wọ́n dojú ìjà kọ Juda, wọ́n gbà á, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Ahasiah, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, Olúwa jẹ Jehoramu ní yà pẹ̀lú ààrùn tí kò ṣe é wòsàn nínú ìfun. 19 Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí ààrùn náà ó sì kú nínú ìrora ńlá. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bu ọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.

20 (C)Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dafidi. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.

Ahasiah ọba Juda

22 (D)Àwọn ènìyàn Jerusalẹmu mú Ahasiah, ọmọ Jehoramu tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Arabia sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.

Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, Ọmọ ọmọbìnrin Omri.

Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀. Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́; Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria.

Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́.

(E)Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sápamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.

Ataliah àti Joaṣi

10 (F)Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Juda run. 11 Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu mú Joaṣi, ọmọkùnrin Ahasiah ó sì jí gbé lọ kúrò láàrín àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti ìyàwó àlùfáà Jehoiada jẹ́ arábìnrin Ahasiah. Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataliah, kí ó má ba à pa á. 12 Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú wọn ni ilé Ọlọ́run fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah ṣàkóso ilẹ̀ náà.

Johanu 14

Jesu sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

14 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú: ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. (A)Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà: ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”

Jesu ni ọnà sí ọ̀dọ̀ Baba

(B)Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?”

(C)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”

Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”

(D)Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ 10 Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 11 (E)Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi: bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá! 12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba. 13 (F)Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. 14 Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.

Jesu ṣe ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́

15 (G)“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16 (H)Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. 18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀. 19 (I)Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú. 20 Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín. 21 Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”

22 Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?”

23 (J)Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. 24 Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.

25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27 (K)Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.

28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ. 29 (L)Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́. 30 (M)Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀: nítorí ọmọ-aládé ayé yí wá, kò sì ní nǹkan kan lòdì sí mi. 31 (N)Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe.

“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò níhìn-ín yìí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.