Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Nehemiah 12-13

Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi

12 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tí ó bá Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua padà:

Seraiah, Jeremiah, Esra,

Amariah, Malluki, Hattusi,

Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,

Iddo, Ginetoni, Abijah,

Mijamini, Moadiah, Bilgah,

Ṣemaiah, Joiaribu, Jedaiah,

Sallu, Amoki, Hilkiah, àti Jedaiah.

Wọ̀nyí ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jeṣua.

Àwọn ọmọ Lefi ni Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda àti Mattaniah ẹni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ni wọn ṣe àkóso orin ìdúpẹ́. Bakbukiah àti Unni, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró sí òdìkejì wọn nínú ìsìn.

10 Jeṣua ni baba Joiakimu,

Joiakimu ni baba Eliaṣibu,

Eliaṣibu ni baba Joiada,

11 Joiada ni baba Jonatani,

Jonatani sì ni baba Jaddua.

12 Ní ìgbé ayé Joiakimu, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà:

ti ìdílé Seraiah, Meraiah;

ti ìdílé Jeremiah, Hananiah;

13 ti ìdílé Esra, Meṣullamu;

ti ìdílé Amariah, Jehohanani;

14 ti ìdílé Malluki, Jonatani;

ti ìdílé Ṣekaniah, Josẹfu;

15 ti ìdílé Harimu, Adna;

ti ìdílé Meraioti Helikai;

16 ti ìdílé Iddo, Sekariah;

ti ìdílé Ginetoni, Meṣullamu;

17 ti ìdílé Abijah, Sikri;

ti ìdílé Miniamini àti ti ìdílé Moadiah, Piltai;

18 ti ìdílé Bilgah, Ṣammua;

ti ìdílé Ṣemaiah, Jehonatani;

19 ti ìdílé Joiaribu, Mattenai;

ti ìdílé Jedaiah, Ussi;

20 ti ìdílé Sallu, Kallai;

ti ìdílé Amoki, Eberi;

21 ti ìdílé Hilkiah, Haṣabiah;

ti ìdílé Jedaiah, Netaneli.

22 Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi ní ìgbà ayé Eliaṣibu, Joiada, Johanani àti Jaddua, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dariusi ará Persia. 23 Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Lefi títí di àkókò Johanani ọmọ Eliaṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn. 24 Àti àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi ni Haṣabiah, Ṣerebiah, Jeṣua ọmọ Kadmieli, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojú wọn láti fi ìyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run.

25 Mattaniah, Bakbukiah, Ọbadiah, Meṣullamu, Talmoni àti Akkubu ni aṣọ́nà tí wọ́n ń sọ yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ní ẹnu-ọ̀nà. 26 Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Joiakimu ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, àti ní ọjọ́ ọ Nehemiah baálẹ̀ àti ní ọjọ́ Esra àlùfáà àti akọ̀wé.

Ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu

27 Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn. 28 A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jerusalẹmu náà ká—láti àwọn abúlé Netofa, 29 Láti Beti-Gilgali, àti láti àwọn agbègbè Geba àti Asmafeti, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnrawọn ní agbègbè Jerusalẹmu. 30 Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú.

31 Mo sì tún yan àwọn olórí Juda láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà Ibodè Ààtàn. 32 Hoṣaiah àti ìdajì àwọn olórí Juda tẹ̀lé wọn, 33 Àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lú wọn, Asariah, Esra, Meṣullamu, 34 Juda, Benjamini, Ṣemaiah, Jeremiah, 35 Pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ìpè, pẹ̀lú u Sekariah ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu, 36 Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—Ṣemaiah, Asareeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneli, Juda àti Hanani—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dafidi ènìyàn Ọlọ́run. Esra akọ̀wé ni ó ṣáájú wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́. 37 Ní ẹnu ibodè orísun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dafidi ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilé Dafidi kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà-oòrùn.

38 Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdìkejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀, 39 Kọjá ẹnu ibodè Efraimu ibodè Jeṣana, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hananeli àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

40 Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè, 41 Àti àwọn àlùfáà Eliakimu, Maaseiah, Miniamini, Mikaiah, Elioenai, Sekariah àti Hananiah pẹ̀lú àwọn ìpè wọn. 42 Àti pẹ̀lú Maaseiah, Ṣemaiah, Eleasari àti Ussi, àti Jehohanani, àti Malkiah, àti Elamu, àti Eseri. Àwọn akọrin kọrin sókè ní abẹ́ alábojútó Jesrahiah. 43 Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jerusalẹmu ní jìnnà réré.

44 Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. 45 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dafidi àti Solomoni ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn. 46 Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní ìgbà Dafidi àti Asafu, ni àwọn atọ́nisọ́nà ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 47 Nítorí náà ní ìgbà ayé Serubbabeli àti Nehemiah, gbogbo Israẹli ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi tókù, àwọn ọmọ Lefi náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀ fún wọn.

Àtúnṣe ìkẹyìn tí Nehemiah ṣe

13 (A)Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún). Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì ènìyàn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrín àwọn Israẹli.

Ṣáájú èyí a ti fi Eliaṣibu àlùfáà ṣe alákòóso yàrá ìkó-nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tobiah pẹ́kípẹ́kí. Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀. Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run. Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílé e Tobiah dà síta láti inú iyàrá náà. Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.

10 Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. 11 Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.

12 Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí. 13 Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

14 Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

15 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. 16 Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. 17 Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́. 18 Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”

19 Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi. 20 Síbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. 21 Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, “Èétijẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru? Bí ẹ̀yìn bá tún dánwò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú yín.” Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. 22 Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.

Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ.

23 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Aṣdodu, Ammoni àti Moabu. 24 Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda. 25 Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín. 26 Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀. 27 Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?”

28 Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.

29 Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi.

30 Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi sí mímọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ 31 Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so.

Rántí mi fún rere, Ọlọ́run mi.

Ìṣe àwọn Aposteli 4:23-37

Àdúrà àwọn onígbàgbọ́

23 Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. 24 (A)Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 25 (B)Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé:

“ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú,
    àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán?
26 Àwọn ọba ayé dìde,
    àti àwọn ìjòyè kó ara wọn
jọ sí Olúwa,
    àti sí ẹni ààmì òróró rẹ̀.’

27 (C)Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi ààmì òróró yàn, 28 Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe. 29 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ. 30 Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

31 Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Àwọn onígbàgbọ́ pín àwọn ohun ìní wọn

32 (D)Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. 33 Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn. 34 Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá. 35 Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.

36 Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi. 37 Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.