Old/New Testament
10 Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni:
Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah.
Sedekiah 2 Seraiah, Asariah, Jeremiah,
3 Paṣuri, Amariah, Malkiah,
4 Hattusi, Ṣebaniah, Malluki,
5 Harimu, Meremoti, Ọbadiah,
6 Daniẹli, Ginetoni, Baruku,
7 Meṣullamu, Abijah, Mijamini,
8 Maasiah, Bilgai àti Ṣemaiah.
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà.
9 Àwọn ọmọ Lefi:
Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli,
10 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah,
Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani,
11 Mika, Rehobu, Haṣabiah,
12 Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,
13 Hodiah, Bani àti Beninu.
14 Àwọn olórí àwọn ènìyàn:
Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani,
15 Bunni, Asgadi, Bebai.
16 Adonijah, Bigfai, Adini,
17 Ateri, Hesekiah, Assuri,
18 Hodiah, Haṣumu, Besai,
19 Harifu, Anatoti, Nebai,
20 Magpiaṣi, Meṣullamu, Hesiri
21 Meṣesabeli, Sadoku, Jaddua
22 Pelatiah, Hanani, Anaiah,
23 Hosea, Hananiah, Haṣubu,
24 Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,
25 Rehumu, Haṣabna, Maaseiah,
26 Ahijah, Hanani, Anani,
27 Malluki, Harimu, àti Baanah.
28 “Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé 29 gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.
30 “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.
31 “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.
32 “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: 33 Nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
34 “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.
35 “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.
36 “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
37 “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. 38 Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí inú ilé ìṣúra. 39 Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí.
“Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”
Àwọn olùgbé tuntun ní Jerusalẹmu
11 Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn. 2 Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jerusalẹmu.
3 (A)Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà. 4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu):
Nínú àwọn ọmọ Juda:
Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;
5 àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.
6 Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.
7 Nínú àwọn ìran Benjamini:
Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joedi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah, 8 àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rún ó-lé-mẹ́jọ (928) ọkùnrin.
9 Joeli ọmọ Sikri ni olórí òṣìṣẹ́ wọn, Juda ọmọ Hasenuah sì ni olórí agbègbè kejì ní ìlú náà.
10 Nínú àwọn àlùfáà:
Jedaiah; ọmọ Joiaribu; Jakini;
11 Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run, 12 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-lé-mẹ́rinlélógún (822) ọkùnrin:
Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah, 13 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó-lé-méjì (242) ọkùnrin:
Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahsai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Immeri, 14 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjì-dínláàdọ́je (128).
Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu.
15 Láti inú àwọn ọmọ Lefi:
Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni;
16 Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;
17 Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà;
Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀;
àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.
18 Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó-lé-mẹ́rin (284).
19 Àwọn aṣọ́nà:
Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án (172) ọkùnrin.
20 Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀.
21 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Ṣiha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.
22 Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run. 23 Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.
24 Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.
25 Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Juda tí ń gbé Kiriati-Arba, àti àwọn ìletò agbègbè e rẹ̀, ní Diboni àti ìletò rẹ̀, ní Jekabseeli. 26 Ní Jeṣua, ní Molada, ní Beti-Peleti 27 Ní Hasari-Ṣuali, ní Beerṣeba àti àwọn agbègbè rẹ̀. 28 Ní Siklagi, ní Mekona àti àwọn ìletò rẹ̀, 29 ní Ẹni-Rimoni, ní Sora, ní Jarmatu, 30 Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé Àfonífojì Hinnomu.
31 Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀. 32 Ní Anatoti, Nobu àti Ananiah, 33 ní Hasori Rama àti Gittaimu, 34 ní Hadidi, Ṣeboimu àti Neballati, 35 ní Lodi àti Ono, àti ní Àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.
36 Nínú ìpín àwọn ọmọ Lefi ni Juda tẹ̀dó sí Benjamini.
Peteru àti Johanu níwájú àwọn Sadusi
4 Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn. 2 Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu. 3 Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan. 4 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000).
5 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu. 6 Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà. 7 Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”
8 Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! 9 Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, 10 Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá. 11 (A)Èyí ni
“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’
12 Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”
13 Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé. 14 Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò. 16 Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ ààmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí. 17 Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”
18 Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu. 19 Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò. 20 Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.”
21 Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe. 22 Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ ààmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.