Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esteri 3-5

Ọ̀tẹ̀ Hamani láti pa àwọn Júù run

Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un.

Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi.

Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.

Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.”

10 Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”

12 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. 13 A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. 14 Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.

15 Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.

Mordekai rọ Esteri láti ràn àwọn Júù lọ́wọ́

Nígbà tí Mordekai gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kun ara, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe sókè ó sì sọkún kíkorò. Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu-ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láààyè láti wọ ibẹ̀. Ní gbogbo ìgbèríko tí àṣẹ ikú ọba dé, ọ̀fọ̀ ńlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú àwẹ̀, ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra.

Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Esteri wá, wọ́n sọ nípa Mordekai fún un, ayaba sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ sí i kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n. Nígbà náà ni Esteri pe Hataki, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Mordekai àti ohun tí ó ṣe é.

Bẹ́ẹ̀ ni Hataki jáde lọ bá Mordekai ní ìta gbangba ìlú níwájú ẹnu-ọ̀nà ọba. Mordekai sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hamani ti ṣe ìpinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù. Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀.

Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ. 10 Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai, 11 “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”

12 Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai, 13 Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. 14 Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?”

15 Nígbà náà ni Esteri rán iṣẹ́ yìí sí Mordekai: 16 “Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.”

17 Bẹ́ẹ̀ ni Mordekai lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Esteri pàṣẹ fún un.

Ẹ̀bẹ̀ Esteri sí ọba

Ní ọjọ́ kẹta Esteri wọ aṣọ ayaba rẹ̀ ó sì dúró sí inú àgbàlá ààfin, ní iwájú gbọ̀ngàn ọba, ọba Jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ nínú gbọ̀ngàn, ó kọjú sí ẹnu-ọ̀nà ìta. Nígbà tí ó rí ayaba Esteri tí ó dúró nínú àgbàlá, inú rẹ̀ yọ́ sí i, ọba sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ṣe súnmọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.

(A)Nígbà náà ni ọba béèrè pé, “Kí ni ó dé, ayaba Esteri? Kí ni o fẹ́? Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajì ọba mi, àní, a ó fi fún ọ.”

Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lú Hamani, wá lónìí sí ibi àsè tí èmi ti pèsè fún un.”

Ọba sì wí pé, “ẹ mú Hamani wá kíákíá, nítorí kí a lè ṣe ohun tí Esteri béèrè fún un.”

Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hamani lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Esteri, “Báyìí pé: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ.”

Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí: Bí ọba bá fi ojúrere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hamani wá ní ọ̀la sí ibi àsè tí èmi yóò pèsè fún wọn. Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba.”

Ìrunú Hamani sí Mordekai

Hamani jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Mordekai ní ẹnu-ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú òun, inú bí i gidigidi sí Mordekai. 10 Ṣùgbọ́n, Hamani kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó lọ sí ilé.

Ó pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ àti Sereṣi ìyàwó rẹ̀ 11 Hamani gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọlá fún un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tókù lọ. 12 Hamani tún fi kún un pé, “Kì í ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Esteri pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la. 13 Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tí ì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Mordekai ará a Júù náà tí ó ń jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ọba.”

14 Ìyàwó rẹ̀ Sereṣi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ bàtà márùn-ún le láàdọ́rin, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Mordekai rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àsè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hamani nínú, ó sì ri igi náà.

Ìṣe àwọn Aposteli 5:22-42

22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.

25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.

27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè. 28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

29 Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! 30 (A)Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. 32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”

33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n. 34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. 35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. 37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”

40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.

41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. 42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìhìnrere náà pé Jesu ni Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.