Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esra 1-2

Kirusi ran àwọn tí a kó nígbèkùn lọ́wọ́ láti padà

(A)Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:

“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:

“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.

Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

Èyí ni iye wọn:

Ọgbọ̀n àwo wúrà30
Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà1,000
Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n29
10 Ọgbọ̀n àdému wúrà30
Irínwó ó-lé-mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn410
Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn1,000

11 Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó-lé-irínwó (5,400).

Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.

Àwọn ìgbèkùn tí o padà

(B)Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá):

Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli:

Àwọn ọmọ

Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)

Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372)

Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775)

Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rìn-lé-méjìlá (2,812)

Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254)

Sattu jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (945)

Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760)

10 Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642)

11 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́tàlélógún (623)

12 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-méjìlélógún (1,222)

13 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́fà (666)

14 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́rìn-dínlọ́gọ́ta (2,056)

15 Adini jẹ́ aádọ́ta-lé-ní-irínwó ó-lé-mẹ́rin (454)

16 Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rin (78)

17 Besai jẹ́ ọrùn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́ta (323)

18 Jora jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112)

19 Haṣumu jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)

20 Gibbari jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95)

21 Àwọn ọmọ

Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)

22 Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà (56)

23 Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128)

24 Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)

25 Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743)

26 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621)

27 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)

28 Beteli àti Ai jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)

29 Nebo jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52)

30 Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìn-dínlọ́gọ́jọ (156)

31 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254)

32 Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320)

33 Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (725)

34 Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345)

35 Senaa jẹ́ egbèjì-dínlógún ó-lé-ọgbọ̀n (3,630)

36 Àwọn àlùfáà:

Àwọn ọmọ

Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973)

37 Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052)

38 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247)

39 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017)

40 Àwọn ọmọ Lefi:

Àwọn ọmọ

Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74)

41 Àwọn akọrin:

Àwọn ọmọ

Asafu jẹ́ méjì-dínláádóje (128)

42 Àwọn aṣọ́bodè:

Àwọn ará

Ṣallumu, Ateri, Talmoni,

Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàn-dínlógóje (139)

43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili:

Àwọn ọmọ

Ṣiha, Hasufa, Tabboati,

44 Kerosi, Ṣiaha, Padoni,

45 Lebana, Hagaba, Akkubu,

46 Hagabu, Ṣalmai, Hanani,

47 Giddeli, Gahari, Reaiah,

48 Resini, Nekoda, Gassamu,

49 Ussa, Pasea, Besai,

50 Asna, Mehuni, Nefisimu,

51 Bakbu, Hakufa, Harhuri.

52 Basluti, Mehida, Harṣa,

53 Barkosi, Sisera, Tema,

54 Nesia àti Hatifa.

55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni:

Àwọn ọmọ

Sotai, Sofereti, Peruda,

56 Jaala, Darkoni, Giddeli,

57 Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili,

Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.

58 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392)

59 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli:

60 Àwọn ọmọ

Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (652)

61 Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà:

Àwọn ọmọ:

Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).

62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63 Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.

64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360). 65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rìn-dínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin. 66 Wọ́n ní ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó-lé-márùn-ún (245) 67 Ràkunmí jẹ́ irínwó ó-lé-márùn-dínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720).

68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.

70 Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.

Johanu 19:23-42

23 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

24 (A)Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”

Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,

“Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
    wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.

25 (B)Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, 26 (C)Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!” 27 Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

Ikú Jesu

28 (D)Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.” 29 Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. 30 Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

31 (E)Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà) nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò. 32 Nítorí náà, àwọn ọmọ-ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. 33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: 34 (F)Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójúkan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. 35 (G)Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀: ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin ba à lè gbàgbọ́. 36 (H)Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.” 37 (I)Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

Ìsìnkú Jesu

38 (J)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò: Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ. 39 (K)Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún lítà. 40 (L)Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn. 41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí. 42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.