Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 5-7

Ìjìyà jẹ́ èso àìṣòdodo

“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn?
    Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?
Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye,
    ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.
Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀,
    ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.
Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,
    a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,
    bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.
Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ,
    tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó,
    àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.
Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,
    tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.
Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,
    gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.

“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,
    ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,
    ohun ìyanu láìní iye.
10 Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé
    tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.
11 Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè
    kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.
12 (A)Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,
    bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.
13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,
    àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.
14 Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán;
    wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.
15 Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,
    lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.
16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,
    àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

17 “Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,
    nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.
18 Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura,
    ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
19 Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,
    àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ
20 Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú
    àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21 A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n,
    bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
22 Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
23 Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀,
    àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
24 Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà,
    ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.
25 Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀
    àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.
26 Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,
    bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.

27 “Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!
    Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”

Ìdáhùn Jobu

Jobu sì dáhùn ó si wí pé:

“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n,
    kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn Òkun lọ:
    nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé
Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
    oró èyí tí ọkàn mi mú;
    ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
    tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?
A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
    tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,
    òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.

“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;
    àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,
    tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,
    àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:
    nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?
    Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
12 Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?
    Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?
13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:
    ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,
    kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé
    bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.
16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,
    àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.
17 Nígbàkúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,
    nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
18 Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,
    wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.
19 Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,
    àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.
20 Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;
    wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.
21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;
    ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.
22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,
    tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?
23 Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,
    tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?

24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́
    kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.
25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó
    ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?
26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe
    àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.
27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,
    ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.
    Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé:
    Ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;
    àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.
30 Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?
    Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?

Jobu ha ni ìrètí bí?

“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?
    Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?
Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji,
    àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,
    òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.
Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’
    Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,
    awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.

“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,
    o sì di lílò ní àìní ìrètí.
Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;
    ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.
Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;
    ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.
Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ,
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.
10 Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11 “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,
    èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,
    èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.
12 Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú,
    tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?
13 Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,
    ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.
14 Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi,
    ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.
15 Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa
    àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.
16 O sú mi, èmi kò le wà títí:
    jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

17 (B)“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?
    Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?
18 Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,
    ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkúgbà!
19 Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,
    tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.
20 Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ.
    Ìwọ Olùsójú ènìyàn?
Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe ààmì itasi níwájú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?
21 Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,
    kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,
    ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”

Ìṣe àwọn Aposteli 8:1-25

(A)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.

Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká

Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.

Filipi ní Samaria

Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.

Simoni onídán

Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun. 10 Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.” 11 Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn. 13 Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á.

14 Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. 15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: 16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. 17 Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

18 Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! 21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. 22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23 (B)Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”

24 Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìhìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.