Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 8-10

Bilidadi

Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé:

“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?
    Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?
    Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,
    ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,
    tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:
    ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,
    òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,
    bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.

“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì
    kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,
    nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10 Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?
    Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀
    tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,
    ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀
13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,
    bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,
    àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,
    yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
16 Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,
    ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17 Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,
    ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18 Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,
    nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19 Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù
    àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.

20 “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
21 títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,
    àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
22 ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
    àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”

Jobu Fún Bilidadi lésì Nípa Ẹ̀kọ́ àti ẹ̀rí Ìdájọ́ Ọlọ́run

Jobu sì dáhùn ó sì wí pé:

“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.
    Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,
    òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀.
Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun;
    ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:
    tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.
Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,
    ọwọ́n rẹ̀ sì mì tìtì.
Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,
    kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,
    ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari, Orioni
    àti Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
10 Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,
    àní ohun ìyanu láìní iye.
11 Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,
    ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12 Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?
    Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13 Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,
    àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.

14 “Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?
    Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?
15 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;
    ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16 Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,
    èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17 Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,
    ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.
18 Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,
    ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19 Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!
    Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20 Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;
    bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.

21 “Olóòótọ́ ni mo ṣe,
    síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,
    ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22 Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:
    ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23 Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,
    yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
24 Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;
    ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;
    bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?

25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,
    wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26 Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;
    bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27 Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,
    èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28 Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,
    èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29 Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,
    ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30 Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,
    tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31 síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò
    ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.

32 “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,
    tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa
    tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34 Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,
    kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí
35 Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;
    ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.

Àròyé Jobu tẹ̀síwájú

10 “Agara ìwà ayé mi dá mi tán,
    èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi,
    èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.
Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi;
    fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.
Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,
    tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
    tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú.
Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?
    Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?
Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,
    ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?
Tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,
    tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?
Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,
    kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

“Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.
    Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.
Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀;
    ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?
10 Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,
    ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?
11 Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,
    ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
12 Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,
    ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

13 “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;
    èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi
    ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.
15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!
    Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.
    Èmi dààmú, mo si wo ìpọ́njú mi.
16 Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún;
    àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
17 Ìwọ sì tún mun àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi
    di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;
    Àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.

18 “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?
    Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
19 Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,
    À bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
20 Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!
    Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.
    Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.
21 Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,
    Àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú.
22 Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,
    Àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,
    Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”

Ìṣe àwọn Aposteli 8:26-40

Filipi àti ìwẹ̀fà Itiopia

26 Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.” 27 Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn, 28 Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah. 29 Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”

30 Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”

31 Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.

32 (A)Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:

“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;
    àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.
33 Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún:
    Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?
    Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”

34 Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35 Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìhìnrere ti Jesu fún un.

36 Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?” 37 Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni.” 38 Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. 39 Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. 40 Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìhìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.