Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
fún mi ní òye kí èmi lè yè.
Ìdáhùn Olúwa
5 (A)“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
6 (B)Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
7 Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
Yóò máa ti inú wọn jáde.
8 Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun
9 Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
10 Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á
11 Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
12 Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí
13 Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
14 Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso
15 Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16 Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17 Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
1 Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi,
Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà.
2 Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.
Mímú kí ìpè àti yíyàn ẹni dájú
3 Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. 4 Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.
5 Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; 6 àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. 7 Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. 8 Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.