Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
15 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama
tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.
Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀;
kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,
nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”
16 Báyìí ni Olúwa wí:
“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún
àti ojú rẹ nínú omijé;
nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,”
ni Olúwa wí.
“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.
17 Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”
ni Olúwa wí.
“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.
18 “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,
‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́
èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.
Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,
nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.
19 Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,
mo ronúpìwàdà,
lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,
èmi lu àyà mi.
Ojú tì mí, mo sì dààmú;
nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’
20 Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára
tí inú mi dùn sí bí?
Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,
síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.
Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,
èmi káàánú gidigidi fún un,”
ni Olúwa wí.
21 “Gbé ààmì ojú ọ̀nà dìde,
ṣe atọ́nà ààmì,
kíyèsi òpópó ọ̀nà geere
ojú ọ̀nà tí ó ń gbà.
Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,
padà sí àwọn ìlú rẹ.
22 Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,
ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin;
Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,
ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”
23 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. 25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”
26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
46 (A)Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.
Bartimeu afọ́jú gba ìwòsàn
47 (B)Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.”
48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.”
49 Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.”
Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká! Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.” 50 Lẹ́sẹ̀kan náà, Bartimeu bọ́ agbádá rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jesu.
51 Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”
Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rabbi, jẹ́ kí èmi kí ó ríran.”
52 (C)Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jesu lọ ní ọ̀nà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.