Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 137

137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
    àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
    tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
    tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
    ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

Àwa ó ti ṣe kọ orin
    Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
    jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
    olórí ayọ̀ mi gbogbo.

Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
    lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
    “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
    ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
    bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
    tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Ẹkun Jeremiah 2:13-22

13 Kí ni mo le sọ fún ọ?
    Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,
    Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,
    kí n lè tù ọ́ nínú,
    Ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.
    Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14 Ìran àwọn wòlíì rẹ
    jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
    tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
    jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.

15 Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ
    pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn
    sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní
    àṣepé ẹwà,
    ìdùnnú gbogbo ayé?”

16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn
    gbòòrò sí ọ;
wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke
    wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.
Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;
    tí a sì wá láti rí.”

17 Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;
    ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
    tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.
Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,
    ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,
    ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

18 Ọkàn àwọn ènìyàn
    kígbe jáde sí Olúwa.
Odi ọmọbìnrin Sioni,
    jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò
    ní ọ̀sán àti òru;
má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,
    ojú rẹ fún ìsinmi.

19 Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,
    bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀
tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi
    níwájú Olúwa.
Gbé ọwọ́ yín sókè sí i
    nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀
tí ó ń kú lọ nítorí ebi
    ní gbogbo oríta òpópó.

20 “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó:
    Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí
Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,
    àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?
Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì
    ní ibi mímọ́ Olúwa?

21 “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀
    sínú eruku àwọn òpópó;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
    ti ṣègbé nípa idà.
Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ;
    Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

22 “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.
Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa
    kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;
àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,
    ni ọ̀tá mi parun.”

1 Johanu 5:1-5

Ìgbàgbọ́ nínú ọmọ Ọlọ́run

(A)Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. (B)Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira, (C)nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?

1 Johanu 5:13-21

Àwọn àfiyèsí ìparí

13 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. 14 (B)Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; 15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.

16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú: èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí. 17 Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀: ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.

18 (C)Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án. 19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà. 20 (D)Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.

21 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.