Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè.
129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá”
ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
láti ìgbà èwe mi wá;
síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
4 Olódodo ni Olúwa:
ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
7 Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Sedekiah bi Jeremiah lẹ́ẹ̀kan sí i
14 Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ pe, Jeremiah òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnu ibodè kẹta nílé Ọlọ́run. Ọba sì sọ fún Jeremiah pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”
15 Jeremiah sì sọ fún Sedekiah pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò nípa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”
16 Ṣùgbọ́n ọba Sedekiah búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremiah wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò nípa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”
17 Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún Sedekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè ọba Babeli, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó ní iná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láààyè. 18 Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babeli, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Babeli. Wọn yóò sì fi iná sun ún, ìwọ gan an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’ ”
19 Ọba Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Babeli, nítorí pé àwọn ará Babeli lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.”
20 Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà. 21 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fihàn mí: 22 Gbogbo àwọn obìnrin tókù ní ààfin ọba Juda ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè ọba Babeli. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé:
“ ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ,
wọ́n sì borí rẹ.
Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀;
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’
23 “Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Babeli. Ìwọ gan an kò ní bọ́ níbẹ̀, ọba Babeli yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.”
24 Nígbà náà ni Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú. 25 Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’ 26 nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jonatani láti lọ kú síbẹ̀.’ ”
27 Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremiah láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti ọba jọ sọ.
28 Jeremiah wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jerusalẹmu:
Ìyànjú èdè-àìyedè àwọn onígbàgbọ́
6 (A)Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? 2 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. 3 Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. 4 Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. 5 Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? 6 Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.
7 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. 9 (C)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ 10 tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 11 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.