Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 102:1-17

Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa

102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
    Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
    ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
    nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.

Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
    egungun mi sì jóná bí ààrò
Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
    mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
Nítorí ohùn ìkérora mi,
    egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
    èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
    àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
    èmi sì rọ bí koríko.

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
    ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
    nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
    àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
    wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
    kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

Jeremiah 29:24-32

Iṣẹ́ pàtàkì tí a rán sí Ṣemaiah

24 Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé, 25 “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu sí Sefaniah ọmọ Maaseiah tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefaniah wí pé, 26 Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin. 27 Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín? 28 Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Babeli wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29 Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì. 30 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé, 31 “Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn ìgbèkùn wí pé: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí ní ti Ṣemaiah, ará Nehalami: Nítorí pé Ṣemaiah ti sọtẹ́lẹ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké. 32 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Wò ó, èmi yóò bẹ Ṣemaiah, ará Nehalami wò, àti irú-ọmọ rẹ̀; òun kì yóò ní ọkùnrin kan láti máa gbé àárín ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí rere náà tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi ni Olúwa wí, nítorí ó ti ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi.’ ”

Efesu 6:10-20

Ìhámọ́ra Ọlọ́run

10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (A)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (B)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.