Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 137

137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
    àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
    tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
    tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
    ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

Àwa ó ti ṣe kọ orin
    Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
    jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
    olórí ayọ̀ mi gbogbo.

Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
    lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
    “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
    ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
    bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
    tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Ẹkun Jeremiah 1:16-22

16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún
    tí omijé sì ń dà lójú mi,
Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,
    kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.
Àwọn ọmọ mi di aláìní
    nítorí ọ̀tá ti borí.”

17 Sioni na ọwọ́ jáde,
    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.
Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu
    pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un
Jerusalẹmu ti di
    ohun aláìmọ́ láàrín wọn.

18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa,
    ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;
    ẹ wò mí wò ìyà mi.
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
    ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.

19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi
    ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.
Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi
    ṣègbé sínú ìlú
nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ
    tí yóò mú wọn wà láààyè.

20 Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!
    Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,
ìdààmú dé bá ọkàn mi
    nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.
Ní gbangba ni idà ń parun;
    ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,
    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.
Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;
    wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.
Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,
    kí wọ́n le dàbí tèmi.

22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;
    jẹ wọ́n ní yà
bí o ṣe jẹ mí ní yà
    nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Ìrora mi pọ̀
    ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Jakọbu 1:2-11

Àwọn ìṣòro àti àwọn ìdánwò

Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun. Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè. Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa; Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. 10 (A)Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. 11 Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.