Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
23 Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,
ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,
nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,
Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,
àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.
24 Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà;
àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde
pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró.
25 “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.
Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé
ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ
àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín.
26 Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó
ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,
ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;
ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
27 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli,
àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
àti pé kò sí ẹlòmíràn:
Ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.
Ọjọ́ Olúwa
28 (A)“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,
èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo;
àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀,
àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
29 Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,
àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,
ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.
30 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun
àti ní ayé,
ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.
31 (B)A á sọ oòrùn di òkùnkùn,
àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,
kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.
32 (C)Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè
orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà:
nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu
ní ìgbàlà yóò gbé wà,
bí Olúwa ti wí,
àti nínú àwọn
ìyókù tí Olúwa yóò pè.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
6 Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
7 Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
6 Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. 7 Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; 8 Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
Òwe Farisi àti agbowó òde
9 Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn; 10 Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde. 11 (A)Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí. 12 (B)Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’
14 (C)“Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.