Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 66:1-12

Fún adarí orin. Orin. Saamu.

66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
    Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
    Ẹ kọrin ìyìnsí i,
Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
    ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
    Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
    wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
    wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.

Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
    Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
    wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
    níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
    ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
    kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.

Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
    jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
    kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
    ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
    o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
    àwa la iná àti omi kọjá
    ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

Jeremiah 25:1-14

Àádọ́rin ọdún nínú oko ẹrú

25 Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli. Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu. Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé. Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”

“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”

Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé. 10 (A)Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. 11 Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.

12 “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé. 13 Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. 14 Àwọn fúnrawọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

2 Timotiu 1:13-18

13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.

16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.