Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 29:1

Lẹ́tà si àwọn ìgbèkùn

29 Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

Jeremiah 29:4-7

Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu ní Babeli: “Ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín. Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ sí i ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá. Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”

Saamu 66:1-12

Fún adarí orin. Orin. Saamu.

66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
    Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
    Ẹ kọrin ìyìnsí i,
Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
    ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
    Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
    wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
    wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.

Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
    Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
    wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
    níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
    ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
    kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.

Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
    jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
    kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
    ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
    o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
    àwa la iná àti omi kọjá
    ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

2 Timotiu 2:8-15

Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:

Bi àwa bá bá a kú,
    àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,
    àwa ó sì bá a jẹ ọba:
Bí àwa bá sẹ́ ẹ,
    òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,
    òun dúró ni olóòtítọ́:
    Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

Òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ

Luku 17:11-19

Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá

11 (A)Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12 (B)Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: 13 (C)Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

14 (D)Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.

17 Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19 (E)Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.