Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 22

22 (A)Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un. Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un. Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀.

Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.

Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.

Nígbà tí o bá kọ́ ilé tuntun, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má ba à mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.

(B)Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èso oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èso ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.

10 Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.

11 Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.

12 (C)Kí o ṣe wajawaja sí etí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlekè rẹ.

Ìrúfin ìgbéyàwó

13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀, 14 tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí ààmì ìbálé rẹ̀.” 15 Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè. 16 Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà, pé “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀. 17 Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú, 18 àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà. 19 Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.

20 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà, 21 (D)wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.

22 Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín Israẹli.

23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, 24 (E)ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.

25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ti pàdé ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ ṣọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a ṣe, ọkùnrin náà nìkan tí ó ṣe èyí ni yóò kú. 26 Má ṣe fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀. 27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.

28 (F)Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàdé wúńdíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá bá a ṣe tí a gbá wọn mú. 29 Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láààyè.

30 (G)Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀; kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀.

Saamu 110-111

Ti Dafidi. Saamu.

110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
    láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
    ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
    láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

(B)Olúwa ti búra,
    kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
    yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
    yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
    yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
    nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.

Isaiah 49

Ìránṣẹ́ Olúwa Náà

49 (A)Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:
    gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:
kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí;
    láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,
    ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:
ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,
    ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,
    Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
(B)Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;
    mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.
Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa,
    èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”

Nísinsin yìí Olúwa wí pé
    ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá
    àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa
    Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi
(C)Òun wí pé:
    “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi
láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò
    àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́.
Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí,
    kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá
    sí òpin ilẹ̀ ayé.”

Ohun tí Olúwa wí nìyìí—
    Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli—
sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra
    lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:
    “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,
àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀,
    nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́,
    Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”

Ìmúpadàbọ̀sípò Israẹli

(D)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:

“Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,
    àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
    láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,
láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò
    àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’
    àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’

“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà
    àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
10 (E)Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,
    tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.
Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,
    tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè-ńlá mi di ojú ọ̀nà
    àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn
    àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀
láti ìwọ̀-oòrùn,
    àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”

13 (F)Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;
    yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;
bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!
    Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú
yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni
    tí a ń pọ́n lójú.

14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀,
    Olúwa ti gbàgbé è mi.”

15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
    kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé
    Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
    ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,
    àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
    gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
    Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
    ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro
    tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,
ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò
    wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ
    yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,
‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;
    ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,
    ‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?
Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;
    A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.
Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?
    A fi èmi nìkan sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí:

    “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà
Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;
    Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn
wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin
    ní èjìká wọn.
23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,
    àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.
Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;
    wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;
    gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi
    ni a kì yóò jákulẹ̀.”

24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,
    tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?

25 Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí:

“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,
    àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;
Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,
    àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ
    ẹran-ara wọn;
wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó
    bí ẹni mu wáìnì.
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀
    pé Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ,
    Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”

Ìfihàn 19

Haleluya

19 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:

“Haleluya!
Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,
    (A)nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.
Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,
    tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

(B)Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:

“Haleluya!
Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

“Àmín, Haleluya!”

(C)Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti èwe àti àgbà!”

Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:

“Haleluya!
Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
(D)Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,
    kí a sì fi ògo fún un.
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,
    aya rẹ̀ sì ti múra tán.
Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀
    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

11 (E)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (F)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (G)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (H)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.

17 (I)Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18 kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.