Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 30

Àlàáfíà lẹ́yìn ìyípadà sí Ọlọ́run

30 Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí. (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà. Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ. Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ. 10 Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.

Ìfifún ìyè tàbí ikú

11 Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ. 12 (B)Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?” 13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì Òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá Òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?” 14 (C)Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí rẹ, ó wà ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.

15 Wò ó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun. 16 Ní èyí tí mo pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè yè, kí ó sì máa bí sí i, kí Olúwa Ọlọ́run lè bù si fún ọ ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ìwọ ń lọ láti gbà á.

17 Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, 18 èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní.

19 Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ, 20 kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

Saamu 119:73-96

Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa

73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
    fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
    nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
    àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
    nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
    nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
    ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
    àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
    kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

Wíwá àlàáfíà

81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
    ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
    èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
    èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
    Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
    tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
    tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
    ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
    ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
    ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
    èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé

89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
    ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
    ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
    nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
    èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
    nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
    èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
    ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.

Isaiah 57

57 Olódodo ṣègbé
    kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;
a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,
    kò sì ṣí ẹni tó yé
pé a ti mú àwọn olódodo lọ
    láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé
    ń wọ inú àlàáfíà;
    wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.

“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
    ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
    Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
tí o sì yọ ahọ́n síta?
    Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
    àti ìran àwọn òpùrọ́?
Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
    àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
    àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
    wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
    Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
    Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
    kí n dáwọ́ dúró?
Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
    níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
    níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn ààmì òrìṣà yín sí.
Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
    ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
    ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
    ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
    ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’
    Ẹ rí okun kún agbára yín,
    nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.

11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
    tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
    tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
    tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
    wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
    ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
    èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
    ni yóò jogún ilẹ̀ náà
    yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́

14 A ó sì sọ wí pé:

“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
    Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15 (A)Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
    ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
    àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
    tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
    rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
    èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
    mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú
    síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
    Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 (B)ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
    Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
    ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
    tí kò le è sinmi,
    tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

Matiu 5

Ìwàásù orí òkè

(A)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.

Ó wí pé:

(B)“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí,
    nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
(C)Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí a ó tù wọ́n nínú.
(D)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,
    nítorí wọn yóò jogún ayé.
(E)Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa
    tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
Alábùkún fún ni àwọn aláàánú,
    nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
(F)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
    nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
    nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
10 (G)Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
    nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
    nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

11 “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. 12 (H)Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀

13 (I)“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 (J)“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15 (K)Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

Ìmúṣẹ òfin

17 “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18 (L)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19 (M)Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20 Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Ìpànìyàn

21 (N)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ 22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. 24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.

25 (O)“Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. 26 Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

Panṣágà

27 (P)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ 28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

Ìkọ̀sílẹ̀

31 (Q)“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ 32 Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

Ìbúra

33 (R)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ 34 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. 35 Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. 36 Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. 37 Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

Ojú fún ojú

38 (S)“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ 39 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. 40 Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. 41 Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. 42 Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.

Fẹ́ràn ọ̀tá rẹ

43 (T)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? 47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.