M’Cheyne Bible Reading Plan
Lílé àwọn orílẹ̀-èdè jáde
7 (A)Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ: Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi: Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ, 2 (B)nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn. 3 (C)Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ, 4 torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá. 5 (D)Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn: Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná. 6 (E)Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.
7 Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn. 8 Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti. 9 Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. 10 Ṣùgbọ́n
àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run;
kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.
11 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.
12 (F)Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín. 13 Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín. 14 A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ. 15 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín. 16 Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.
17 Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?” 18 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn: Ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti. 19 Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù. 20 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé. 21 Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀. 22 Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò nígbà yín láààyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko igbó má ba à gbilẹ̀ sí i láàrín yín. 23 Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run. 24 Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run. 25 Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín. 26 Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má ba à di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kórìíra rẹ̀ kí ẹ sì kà á sí ìríra pátápátá, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.
ÌWÉ KẸRIN
Saamu 90–106
Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run
90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4 (A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ
nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà
35 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
2 Ní títanná yóò tanná;
yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
àti ẹwà Ọlọ́run wa.
3 (A)Fún ọwọ́ àìlera lókun,
mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
òun yóò wá láti gbà yín là.”
5 (B)Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Ìwé àti Ọ̀dọ́-àgùntàn
5 (A)Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. 2 Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” 3 Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. 4 Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. 5 (B)Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”
6 (C)Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. 7 Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. 8 (D)Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. 9 (E)Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:
“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,
àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:
nítorí tí a tí pa ọ,
ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,
àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:
10 (F)Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:
wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”
11 (G)Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 12 Wọn ń wí lóhùn rara pé:
“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa,
láti gba agbára,
àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,
àti ògo, àti ìbùkún.”
13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,
“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,
fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn
náà láé àti láéláé.”
14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.