M’Cheyne Bible Reading Plan
32 Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;
ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,
bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,
bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
3 Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa,
Háà, ẹ yin títóbi Ọlọ́run wa!
4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,
gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.
Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,
Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
5 (A)Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.
6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,
Háà, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?
Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,
tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
7 Rántí ìgbà láéláé;
wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.
Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,
àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
8 Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,
ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.
9 Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.
10 Ní aginjù ni ó ti rí i,
ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.
Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,
ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,
tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì
gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.
12 Olúwa ṣamọ̀nà;
kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.
13 Ó mú gun ibi gíga ayé
ó sì fi èso oko bọ́ ọ.
Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,
àti òróró láti inú akọ òkúta wá,
14 Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn
àti ti àgbò ẹran
àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani
tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.
15 Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;
ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.
O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ
o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.
16 Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,
ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.
17 Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,
ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,
ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,
ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.
18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.
21 (B)Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.
Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;
èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,
yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.
Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀
yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,
ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.
Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.
25 Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.
Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.
26 Mo ní èmi yóò tú wọn ká
èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,
27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má
ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;
kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.
29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!
30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,
tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàárùn-ún sá,
bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,
bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?
31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,
àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.
32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu
àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.
Èso àjàrà wọn kún fún oró,
Ìdì wọn korò.
33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,
àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.
34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́
èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?
35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san; Èmi yóò san án fún wọn
ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;
ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé
ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”
36 Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀
nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán
tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.
37 Yóò wí pé: “Òrìṣà wọn dà báyìí,
àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
39 “Wò ó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!
Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,
Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:
Èmi ti wà láààyè títí láé,
41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,
Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi
Èmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.
42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”
43 (C)Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;
yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀
yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.
44 Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni. 45 Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. 46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. 47 Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”
Ikú Mose lórí òkè Nebo
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé, 49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Olórin pa òfin Olúwa mọ́
121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
fún mi ní òye kí èmi lè yè.
Ẹ̀ṣẹ̀, ìjẹ́wọ́ àti ìràpadà
59 Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,
tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;
Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín
tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
3 Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,
àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.
Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,
ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.
4 Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;
kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;
wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà
5 Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀
wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,
àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
6 Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;
wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.
Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
7 (A)Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;
wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;
ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe ààmì ọ̀nà wọn.
8 Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;
kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn
wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,
kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
9 Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,
àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.
A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;
ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri
tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.
Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;
láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
11 Gbogbo wa là ń ké bí i beari;
àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà
A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà
fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.
Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,
àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,
kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,
dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,
pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,
àti ti òdodo dúró lókèèrè;
òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,
òdodo kò sì le è wọlé.
15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.
Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 (B)Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
19 (C)Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.
20 (D)“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,
sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó
ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.
21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni Olúwa wí.
Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkejì
7 (A)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
3 (B)“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.
6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ.
Béèrè, kànkùn, wá kiri
7 (C)“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? 10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? 12 Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.
Ọ̀nà tóóró àti ọnà gbòòrò
13 (D)“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
Igi àti èso rẹ̀
15 (E)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 (F)“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé
24 (G)“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
28 (H) Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, 29 Nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.