Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 27:1-28:19

Pẹpẹ ní orí òkè Ebali

27 Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́. Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”

Ègún ní orí òkè Ebali

Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí. 10 Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

11 Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

12 Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

14 Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:

15 (A)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

16 (B)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

17 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

18 (C)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

19 (D)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

20 (E)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

21 (F)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

23 (G)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

26 (H)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

Ìbùkún fún ìgbọ́ràn

28 (I)Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ:

Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.

Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.

Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.

Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.

Olúwa yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 10 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ Olúwa, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ. 11 Olúwa yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.

12 Olúwa yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan. 13 Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé. 14 Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.

Ègún fún àìgbọ́ràn

15 Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:

16 Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

17 Ègún ni fún Agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.

18 Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

19 Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

Saamu 119:1-24

119 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
    ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
    tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
    wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
    kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
    láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
    nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
    bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀:
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
    má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
    kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12 Ìyìn ni fún Olúwa;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
    gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
    bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
    èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
    èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.

Ohun ìyanu tí o wà nínú òfin rẹ̀

17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
    èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
    ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
    Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
    nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
    tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
    nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
    ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
    àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.

Isaiah 54

Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni

54 (A)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
    ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
    ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
    ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
    ni Olúwa wí.
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
    fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
    sọ okùn rẹ di gígùn,
    mú òpó rẹ lágbára sí i.
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
    ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
    Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
    Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
    a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Olúwa yóò pè ọ́ padà
    àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
    obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
    tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
    mú ọ padà wá.
Ní ríru ìbínú.
    Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
    Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
    ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
    nígbà tí mo búra pé àwọn omi
Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
    Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
    tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
    tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
    ni Olúwa, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.

11 (B)Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
    tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
    àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
    àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
    àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
13 (C)Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
    àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
    ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun
    Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
    kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.

16 “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ
    tí ń fẹ́ iná èédú iná
tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.
    Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,
    àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́
    ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.
Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
    èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

Matiu 2

Ìbẹ̀wò àwọn amòye

(A)Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. (B)Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi? (C)Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

(D)“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea,
    ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda;
nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,
    Ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”

Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. 10 Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. 11 (E)Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. 12 (F)Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

A gbé Jesu sálọ sì Ejibiti

13 Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.”

14 Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 15 (G)ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

16 Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. 17 Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé:

18 (H)“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,
    ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá,
Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀.
    Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀
nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

Ìpadà sí Nasareti

19 (I)Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti 20 Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.”

21 Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Akelausi ni ó ń jẹ ọba ní Judea ní ipò Herodu baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Galili lọ, 23 (J)ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Nasareti. Nígbà náà ni èyí tí a sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Nasareti.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.