M’Cheyne Bible Reading Plan
Àjọ ìrékọjá
16 (A)Ẹ kíyèsi oṣù Abibu, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Abibu yìí ni ó mú un yín jáde ní Ejibiti lóru. 2 Ẹ fi ẹran kan rú ẹbọ bí ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. 3 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Ejibiti: kí ẹ bá à lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Ejibiti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. 4 Kí a má sì ṣe rí àkàrà wíwú ní ọ̀dọ̀ rẹ nínú ilẹ̀ rẹ ní ijọ́ méje. Kí ìwọ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹ́kù nínú ẹran tí ìwọ ó fi rú ẹbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
5 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín 6 bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 7 Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín. 8 Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.
Ayẹyẹ àwọn ọ̀sẹ̀
9 Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà. 10 Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín. 11 Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín. 12 Ẹ rántí pé, ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.
Ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé
13 Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán. 14 Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín. 15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ̀yin kí ó fi ṣe ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.
16 Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ kí ó farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ní ibi tí yóò yàn. Níbi àjọ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀sẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú Olúwa ní ọwọ́ òfo. 17 Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀.
Àwọn adájọ́
18 Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. 19 (B)Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. 20 Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.
Sí sin ọlọ́run mìíràn
21 (C)Ẹ má ṣe ri ère òrìṣà Aṣerah sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún Olúwa Ọlọ́run yín. 22 Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín kórìíra.
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo
43 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9 Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí
wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,
yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
Àánú Ọlọ́run àti àìṣòdodo Israẹli
14 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli;
“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,
gbogbo ará Babeli
nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,
Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,
ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi
ìwọ Israẹli.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
Ẹranko kan tí n ti inú okun jáde wá
13 (A)Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú Òkun jáde wá, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, lórí àwọn ìwo náà ni adé méje wà, ni orí kọ̀ọ̀kan ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà. 2 Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí beari ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dragoni náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá. 3 Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a sá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà. 4 Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dragoni náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”
5 (B)A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì. 6 Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run. 7 (C)A sì fún un láti máa bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀. 8 Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
9 (D)Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.
10 (E)Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbèkùn,
ìgbèkùn ni yóò lọ;
ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,
ni a ó sì fi idà pa.
Níhìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.
Ẹranko jáde nínú ilẹ̀
11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn. 14 (F)Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè. 15 (G)A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà. 16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; 17 àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní ààmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí ààmì orúkọ rẹ̀.
18 Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ọgọ́ta-ẹẹ́fà. (666).
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.