Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 24

24 (A)Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, tí ó sì gbe ní ìyàwó, yóò sì ṣe, bí obìnrin náà kò bá rí ojúrere ní ojú ọkùnrin náà, nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan lára rẹ̀, ǹjẹ́ kí ó kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún obìnrin náà, kí ó sì fi lé e lọ́wọ́, kí ó sì ran jáde kúrò nínú ilé rẹ̀, tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ, àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú, nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú Olúwa. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.

Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.

(B)Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsè, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní pàṣípàrọ̀ n nì.

(C)Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tà á, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹ ní láti wẹ búburú kúrò láàrín yín.

(D)Ní ti ààrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pàṣẹ fún wọn. Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.

10 Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí. 11 Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògo rẹ jáde wá fún ọ. 12 Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ tálákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ. 13 Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

14 (E)Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ. 15 San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.

16 Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.

17 (F)Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí. 18 Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

19 (G)Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. 20 Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. 21 Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. 22 Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

Saamu 114-115

114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
    ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
    Israẹli wà ní ìjọba.

(A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
    Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
    òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
    Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
    àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
    ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
    àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Isaiah 51

Ìgbàlà ayérayé fún Sioni

51 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
    àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
    àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
ẹ wo Abrahamu baba yín,
    àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
    Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
    yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
    àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
    ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.

“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
    gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi:
Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
    ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
    ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
    sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
    wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
(A)Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
    wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
    ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
    Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
    òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.

“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
    ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín:
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
    tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ;
    Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
    àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”

Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
    Ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
    àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
    tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
    àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
    tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
    Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
    Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
    ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.
    Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,
    àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,
    ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run
tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́
nítorí ìbínú àwọn aninilára,
    tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun?
    Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ
    wọn kò ní kú sínú túbú wọn,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
15 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí
ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ
    mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́
Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
    ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,
àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé,
    ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

Ago ìbínú Olúwa

17 Jí, jí!
    Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu,
ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa
    ago ìbínú rẹ̀,
ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀
    tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
18 Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí
    kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà
nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́
    kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.
19 Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—
    ta ni yóò tù ọ́ nínú?
Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà
    ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
20 Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;
    wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,
gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.
    Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́
    àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

21 Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,
    tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì
22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí,
    Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́,
“Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ
    ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n;
láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi,
    ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
23 Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́,
    àwọn tí ó wí fún ọ pé,
‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’
    Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”

Ìfihàn 21

Jerusalẹmu tuntun

21 (A)Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. (B)Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. (C)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. (D)Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”

(E)Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”

(F)Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. (G)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. (H)Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”

Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10 (I)Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 11 Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; 12 (J)Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15 (K)Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. 16 Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. 17 Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. 18 A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. 19 (L)A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni ẹ̀kẹrin, emeradi, 20 ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, bereli; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. 21 Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ pearli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

22 Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. 23 (M)Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. 24 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. 25 (N)A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀. 26 Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀. 27 (O)Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.