Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 102

Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa

102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
    Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
    ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
    nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.

Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
    egungun mi sì jóná bí ààrò
Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
    mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
Nítorí ohùn ìkérora mi,
    egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
    èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
    àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
    èmi sì rọ bí koríko.

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
    ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
    nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
    àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
    wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
    kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
    àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
    láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
    àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
    àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
    ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
    ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
    “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
    gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
    wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
    ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
    a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”

Saamu 142-143

Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.

142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
    Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
    ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
    ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
    kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
    kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
    èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
    ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

Fi etí sí igbe mi,
    nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
    nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
    kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
    nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

Saamu ti Dafidi.

143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
    fetísí igbe mi fún àánú;
    nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
(A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
    nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
    tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
Ọ̀tá ń lépa mi,
    ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
    bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
    ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
    èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
    mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
    òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
    ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
    kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
    nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
    nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
    nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
    darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.

11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
    nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
    run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
    nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.

Jeremiah 20:7-11

Ìráhùn Jeremiah

Olúwa, o tàn mí jẹ́,
    o sì ṣẹ́gun.
Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,
    gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
    èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù
    àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
    tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
    nínú egungun mi
Agara dá mi ní inú mi
    nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,
    ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo
Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!
    Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró
kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,
    Bóyá yóò jẹ́ di títàn,
nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,
    àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.
    Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,
wọn kì yóò sì borí.
    Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.
    Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.

1 Kọrinti 10:14-17

Oúnjẹ òrìṣà àti oúnjẹ alẹ́ Olúwa

14 (A)Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnrarẹ̀ ohun tí mo sọ. 16 (B)Ǹjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17 Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo.

1 Kọrinti 11:27-32

27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.

Johanu 17

Jesu gbàdúrà fún ara rẹ̀

17 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé:

“Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà.

Jesu gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn

“Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. (C)Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. 10 Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. 11 (D)Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. 12 (E)Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.

13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. 14 (F)Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. 16 Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 17 Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. 18 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. 19 Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.

Jesu gbàdúrà fún gbogbo onígbàgbọ́

20 “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; 21 (G)Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. 22 Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; 23 Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi.

24 (H)“Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

25 “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. 26 Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.