Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 66-67

Fún adarí orin. Orin. Saamu.

66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
    Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
    Ẹ kọrin ìyìnsí i,
Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
    ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
    Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
    wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
    wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.

Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
    Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
    wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
    níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
    ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
    kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.

Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
    jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
    kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
    ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
    o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
    àwa la iná àti omi kọjá
    ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
    kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
    nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
    àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
    èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.

16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
    ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
    Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
    Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
    ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
    ẹni tí kò kọ àdúrà mi
    tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.

67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
    kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
    ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
    nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
    ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
    Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
    àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

Saamu 19

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

19 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
    Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
    wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
    níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
(A)Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
    ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
    Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
    òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
    àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
    kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin Olúwa,
    ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
    ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
    òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
    ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
    àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
    Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
    má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
    èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

Jeremiah 14:1-9

Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà

14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

“Juda káàánú,
    àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
    igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
    wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
    Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Ilẹ̀ náà sán
    nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
    fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
    torí pé kò sí koríko.
Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
    wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
    nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
    wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
    a ti ṣẹ̀ sí ọ.
Ìrètí Israẹli;
    ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
    bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
    bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
    orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
    má ṣe fi wá sílẹ̀.

Jeremiah 14:17-22

17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:

“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
    ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
    ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
    pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
    Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
    èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
    ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
    Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
    tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
    ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
    ìpayà là ń rí.
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
    àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
    lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
    má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
    kí o má ṣe dà á.
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
    Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
    Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

Galatia 4:21-5:1

Hagari àti Sara

21 Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin ohun ti òfin sọ. 22 (A)Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin. 23 (B)Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

24 Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari. 25 Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27 (C)Nítorí a ti kọ ọ́ pé,

“Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn
    tí kò bímọ,
bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,
    ìwọ tí kò rọbí rí;
nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀
    yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

28 Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. 29 (D)Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí. 30 (E)Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.” 31 Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.

Òmìnira nínú Jesu

Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.

Marku 8:11-21

11 (A)Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún ààmì láti ọ̀run. 12 Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá ààmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si ààmì tí a ó fi fún ìran yín.” 13 (B)Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.

Ìwúkàrà àwọn Farisi àti Herodu

14 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. 15 (C)Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”

16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?”

17 (D)Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? 19 (E)Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?”

Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

20 (F)“Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”

21 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.